Sunday Igboho b’Alaroye sọrọ: Eyi nidi ti mo fi gbe Gani Adams lọ sile-ẹjọ

Jọkẹ Amọri

Ajijagbara ọmọ Yoruba nni, Oloye Majasọla Sunday Adeyẹmọ, ti gbogbo eeyan mọ si Sunday Igboho, ti sọ idi pataki to fi gbe igbesẹ lati pe Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba, Oloye Gani Adams, lẹjọ si kootu kan to wa niluu Ibadan.

L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrin, oṣu yii, ni Igboho ṣalaye ọrọ naa fun ALAROYE lasiko ti akọroyin wa pe e lori foonu lati beere idi to fi yi ipinnu rẹ pada lori ọrọ ẹjọ naa.

Ṣe ṣaaju ni Igboho ti kọkọ sọ pe oun ko ni i pe Aarẹ Gani Adams lẹjọ, nitori awọn agbaagba Yoruba kan ti sọ pe ki oun jeburẹ lori ọrọ naa.

Sunday Igboho ti wọn tun maa n pe ni Igboho Ooṣa ṣalaye fun akọroyin wa pe nigba ti oun tun ọrọ naa wo, nitori ọjọ iwaju, ati nitori awọn ọmọ oun, loun ṣe pinnu lati gbe ọrọ naa lọ si kootu.

Igboho ni, ‘‘ALAROYE, ẹyin naa mọ orileede yii pe ko si ohun ti ko le ṣẹlẹ, ko si ohun ti wọn ko le yi mọ-ọn-yan lọwọ, ti mo ba dakẹ, ti mo ni mi o wi nnkan kan lori ẹsun banta banta ti wọn fi kan mi ti ki i ṣe ootọ yii, to ba dọjọ iwaju tawọn eeyan fi n bu awọn ọmọ mi tabi ti wọn n lo o ta ko wọn nkọ.

‘‘Abi ti awọn eeyan bẹrẹ si i fi bu mi, ti wọn si gba gbogbo ohun ti Gani Adams sọ nipa mi gbọ, ti wọn si fi n bu mi tabi huwa si mi, kin ni ki n maa sọ. Wọn ni Tinubu lo n lo mi, oun lo gbowo fun mi, oun lo n ran mi niṣẹ, bawo leeyan ṣe maa pa iru irọ bantabanta bẹẹ mọ mi.

‘‘Gbangba ni mo ti n sọ ọ, ẹẹkan naa ni mo ri Tinubu ri laye mi, mi o gbowo lọwọ ẹnikẹni, mi o si ba ẹnikẹni ṣepade. Ṣebi mo sọ fun yin pe kẹ ẹ beere lọwọ Tayọ Ayinde, to ba ṣe pe loootọ ni mo pade rẹ nibikibi abi to ba ṣe pe loootọ lo gbowo fun mi.

‘‘Ẹ tun gbọ irọ to pa mọ mi pe mo mọ nipa iku Oloye Bọla Ige, emi, mi o ṣe oṣelu, ilu Mọdakẹkẹ ni mo wa ni gbogbo asiko yẹn, ko si si ibikibi ti wọn ti ki iku Baba Bọla Ige mọ mi nigba ti wọn gbe ọrọ naa lọ sile-ẹjọ, bawo leeyan yoo ṣe waa pa iru irọ bẹẹ mọ mi ti mi o ni i sọ pe ko ko ẹri awọn ohun to sọ yii kalẹ. Mi o mọ ohun ti mo ra nigba Aarẹ ti wọn fi le pa iru irọ bẹẹ mọ mi. Tori ọjọ ọla temi ati tawọn ọmọ mi ni mo ro ti mo fi gba ile-ẹjọ lọ pe ko waa ṣalaye gbogbo awọn ohun to sọ yii, ko si ko ẹri wa lati fi gbe ọrọ rẹ lẹsẹ, ki kootu le ba wa foju ofin wo o’’.

Nigba ti ALAROYE beere igba ti ajijagbara ọmọ Yoruba yii maa pada wa si orileede Naijiria, Igboho ni ki i ṣe pe ko wu oun lati wa sile, nigba to jẹ ojulowo ọmọ orileede Naijiria loun, ṣugbọn ijọba Naijiria ni ko ti i gba oun laaye lati wọle. ‘‘Kin ni mo fẹẹ maa duro ṣe lẹyin-odi, nigba to jẹ pe gbogbo iṣẹ ati okoowo mi, Naijiria lo wa, ki i ṣe didun inu mi lati fi iṣẹ mi silẹ, nitori a ki i foju oloju ṣowo ka jere, ṣugbọn ijọba ko ti i fun mi laṣẹ lati wọle pada ni’’.

Nigba ti ALAROYE beere igbesẹ to n gbe lati ri i pe o pada si orileede baba rẹ, Igboho ni ko si agbara naa lọwọ oun, ijọba lo ni aṣẹ lati faaye gba oun lati pada si ilẹ Naijiria.

ALAROYE beere boya o ti n gbiyanju lati ri Aarẹ Tinubu atawọn alẹnulọrọ lori ọrọ yii, Igboho ni oun ko ti i ṣe bẹẹ. Ọkunrin naa ni oun gbagbọ pe ọrọ naa maa niyanju laipẹ.

Ninu alaye to ṣe fun wa nigba ta a beere pe bawo lo ṣe wa n gbọ bukaata ile rẹ nigba ti ko si iṣẹ kankan to n ṣe, ọkunrin naa ni aanu Ọlọrun loun n jẹ.

Ṣugbọn pẹlu gbogbo rẹ naa, Sunday Igboho loun ko kabaamọ pe oun ja fun ilẹ Yoruba. O ni bi ijẹgaba awọn Fulani ba tun ṣẹlẹ, gbogbo iriri ti oun la kọja ṣiwaju ko ni i di oun lọwọ tabi da omi tutu si oun lọkan lati ja fun Yoruba ti i ṣe iran oun.

Leave a Reply