Mi o ba ẹnikankan sọ pe mo ko arun ibalopọ lara ọkọ mi-Iyawo Mohbad

Adewale Adeoye

Wunmi Alọba ti i ṣe iyawo Oloogbe Ilerioluwa Alọba, ẹni tawọn eeyan mọ si Mohbad, ti sọ pe oun ko figba kankan sọ fẹnikẹni ri pe oun ko arun ibalopọ lara ọkọ oun to ti doloogbe, ati pe oun ko mọ ibi ti ibatan oun, Omidan Karimot Ogunbayọ, ti gbọ iroyin ọhun pe Oloogbe Mohbad ko arun ibalopọ ran oun nigba aye rẹ, tabi pe o maa n lu oun nigba gbogbo tija kekere kan ba ti waye laarin awọn.

Gbara ti Oloogbe Mohbad ku tan ni oniruuru iroyin ti n lọ nigboro, tawọn araalu si n sọ oriṣiiriṣii ọrọ lori rẹ. Lara awọn ahesọ to n jade nigba naa ni eyi ti ọkan lara ibatan Wunmi ti i ṣe iyawo oloogbe sọ pe Oloogbe Mohbad ko arun ibalopọ ran an nigba to wa laye.

Omidan Karimot sọrọ buruku si Alagba Joseph Alọba ti i ṣe Baba Mohbad, pe ọmọ rẹ wa ninu ẹgbẹ okunkun, ati pe o maa n ko arun ibalopọ ran Wunmi lọpọ igba. Ṣugbọn laipẹ yii ni Wunmi Alọba bọ sita to si sọ ọ di mimọ pe oun ko figba kankan sọ fẹnikẹni ri pe ọkọ oun, Oloogbe Mohbad, ko arun ibalopọ ran oun. Ati pe ko soootọ ninu ọrọ to sọ pe  Mohbad maa n lu oun ti ija kekere ba waye laarin awọn nigba to wa laye.

O ni, ‘’Mi o ba ẹnikankan sọrọ naa ri, mi o mọ ibi ti ibatan mi ti gbọrọ naa rara’’.

 

Leave a Reply