Ẹwọn ọdun meje ni adajọ ju ọlọpaa to yinbọn paayan l’Ekoo si

Aderohunmu Kazeem

Lọdun 2016 ni Ologunowa Ojo to wa ninu iṣẹ ọlọpaa nigba naa fi ibinu yinbọn fun ọmọkunrin kan, Taiye Akande, ni ibadi, tiyẹn si ṣe bẹẹ ku mọ ọn lọwọ.

Adajọ Oluwatoyin Taiwo ti sọ pe ki wọn ju Ojo sẹwọn ọdun meje bayii lẹyin to jẹbi ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan an.

Ọjọ kẹta, oṣu keji, ọdun 2016, ni wahala ọhun bẹrẹ nigba ti ede aiyede bẹ silẹ laarin Ojo ati Taiye Akande. Ileeṣẹ kan to maa n ta ọkada, iyẹn Frajend Investment, to wa niluu Shapati, lẹgbẹẹ Ajah, ni ọlọpaa yii n ṣọ nigba naa.

Ọrọ kekere kan ni wọn sọ pe wọn fa mọra wọn lọwọ lori bi Akande ṣe jokoo sori iganna ti wọn fi yi ọgba ileeṣẹ naa ka. Nibi ti wọn si ti n fa a mọra wọn lọwọ ni ọlọpaa yii ti yinbọn lu u nibadi, loju ẹsẹ ni wọn sare gbe e lọ si ọsibitu Jẹnẹra to wa ni Akọdo, nibẹ naa ni ẹmi ti bọ lara Akande.

Iṣẹlẹ yii naa lo mu ileeṣẹ ọlọpaa ṣewadii ọkunrin yii, ti wọn si yọ ọ lẹnu iṣẹ ki ile-ẹjọ too tun ju u sẹwọn ọdun meje bayii.

Bo tilẹ jẹ pe Ojo sọ pe oun ko mọ ọn mọ pa a, ati pe ṣeeṣi ni ibọn ọhun ba a nibi to ti n lọ ọ mọ oun lọwọ, sibẹ, Adajọ Oluwatoyin ti sọ pe ọpọ ẹmi lo ti ṣofo lọwọ awọn ọlọpaa, ti wọn si ti fi aibikita pa danu.

O ni fun idi eyi, ko tete lọọ ṣe ọdun meje lẹwọn, ki ọrọ ẹ lẹ jẹ arikọgbọn fawọn yooku ẹ.

 

Leave a Reply