Ẹwọn ọdun mẹwaa ni wọn ju ‘Mama Boko Haram’ si

Monisọla Saka

Aisha Alkali Wakil, ti wọn maa n pe ni Mama Boko Haram, atawọn ọkunrin meji kan, Tahiru Saidu Daura ati Prince Lawal Soyade, ti rẹwọn ọlọdun mẹwaa he, nitori jibiti ologoji miliọnu Naira ti wọn lu.

Gẹgẹ bi Dele Oyewale, ti i ṣe agbẹnusọ ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ati ajẹbanu lorilẹ-ede Naijiria, Economic and Financial Crimes Commission (EFCC), ṣe sọ lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejila, oṣu Keji, ọdun yii, o ni Onidaajọ Umaru Fadawu, ti Ile-ẹjọ giga to wa niluu Maiduguri, olu ilu ipinlẹ Borno, ti ran awọn mẹtẹẹta ọhun lẹwọn lẹyin ti ajọ EFCC ka ẹsun meji si wọn lọrun.

Ẹsun mejeeji ti wọn ka si Wakil, Daura ati Soyade lọrun ni pe, wọn jẹbi igbimọ-pọ ati fifi ọgbọn jibiti gba miliọnu lọna ogoji Naira lọwọ Ọgbẹni Abubakar.

Awọn ọdaran mẹtẹẹta yii ni wọn pe ni oludari ati adari ileeṣẹ ẹlẹyinju aanu ti ki i ṣe tijọba, Complete Care and Aid Foundation. Ọgbẹni Saidu Mukhtar, to jẹ ọkan lara awọn ọdaran, amọ to ti na papa bora bayii, lo fi ọgbọn jibiti gba ogoji miliọnu Naira lọwọ oludasilẹ ileeṣẹ Duty-Free Shop Limited, Bashir Abubakar, pẹlu adehun pe awọn yoo ba wọn dowo-pọ lati ta ẹrọ igbalode ti wọn fi n ya fọto egungun (X-ray machines), ati Solar fun un.

Ẹṣẹ ti Oyewale ni o ta ko ofin ilẹ Naijiria lori iwa ọdaran ti ọdun 2006. Ṣugbọn awọn ọdaran bẹbẹ pe awọn ko jẹbi ẹ.

Ṣugbọn agbẹjọro ijọba, A.I. Arogha, pe ẹlẹrii mẹrin, to si tun ko ẹri bii mẹtadinlogun siwaju ile-ẹjọ lori ọrọ yii.

Ninu alaye Oyewale gẹgẹ bo ṣe wa ninu atẹjade to fi lede, o ni, “Irinajo awọn ọdaran mẹtẹẹta yii lọ si ọgba ẹwọn bẹrẹ nigba ti ẹni kan kọwe ẹsun pe wọn fọgbọn gba obitibiti owo lọwọ oun, pẹlu adehun pe wọn yoo ko ẹrọ X-ray ati ohun eelo ina igbalode to n lo oorun (solar energy), wa si ileeṣẹ ẹlẹyinju aanu ti ko si labẹ akoso ijọba kan, iyẹn Complete Care and Aid Foundation. Bi wọn ṣe kọ lati ko awọn ohun eelo yii wa, ti wọn ko si da ogoji miliọnu ọhun pada lo mu ki ọkunrin naa kọwe ẹsun ta ko wọn”.

Lẹyin ti Adajọ Fadawu gbe awọn ẹri naa yẹwo lo paṣẹ pe kawọn olujẹjọ mẹtẹẹta lọọ faṣọ penpe roko ọba fọdun mẹwaa.

Bakan naa lo tun pa wọn laṣẹ lati pawọ-pọ da ogoji miliọnu Naira (40m) pada fun Ọgbẹni Bashir Muhammad.

 

Leave a Reply