Ina sọ nile-ẹjọ giga ipinlẹ Kwara, ọpọ dukia jona gburugburu

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

L’ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtala, oṣu Keji yii, ni ina sọ nile-ẹjọ giga ipinlẹ Kwara, eyi to wa ni agbegbe G.R.A, niluu Ilọrin, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ naa.

ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago meje aabọ kọja iṣẹju mẹta ni ina ṣẹ yọ lojiji lẹka to n gba iwe ipẹjọ ati ẹka to n ri si iwe ipẹjọ (registry and litigation department), ti gbogbo ẹka naa si jona gburugburu.

Alukoro ajọ panapana ni Kwara, Hassan Adekunle, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fawọn oniroyin, o ni ileeṣẹ panapana gba ipe pajawiri ni nnkan bii aago meje aabọ kọja iṣẹju mẹta pe ile-ẹjọ giga tipinlẹ Kwara ti n jona, ti awọn si tete gbe ọkọ omi gunlẹ sibi iṣẹlẹ naa.

O tẹsiwaju pe bi awọn ṣe de sibi iṣẹlẹ naa lawọn lo ọgbọn inu ati oye ikun lati fi kapa ina ọhun ko maa baa ran mọ awọn ọfiisi to wa lagbegbe rẹ.

O ni iwadii fidiẹ ẹ mulẹ pe ina ẹlẹntiriiki to ṣẹju lo ṣokunfa ijamba ina ọhun. O ni ọfiisi ogoji ati iya idajọ mẹta lo wa ninu ile kootu naa, ṣugbọn ẹka meji pere lo jona.

 

Leave a Reply