Damilare fo fẹnsi lọọ ji jẹnẹretọ nla l’Abẹokuta, ni wọn ba ka a mọ

Faith Adebọla

Afaimọ ni ọkunrin ti wọn pe ni Damilare yii ko ni i di ẹni idalẹbi ni kootu laipẹ, tori akolo ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ, nibi ti wọn ti n ṣewadii ẹsun idigunjale, lolu-ileeṣẹ awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun to wa l’Eleweeran, l’Abẹokuta, ni afurasi ọdaran naa wa bayii. Niṣe ni jagunlabi lọọ fo fẹnsi ile onile, o ji jẹnẹretọ kan, ibi to ti n tu u, ko le ribi gbe awọn ẹya-ara rẹ sa lọ ni wọn ka a mọ, to fi dero ahamọ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Ogun, SP Ọmọlọla Odutọla, ṣalaye ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ s’ALAROYE lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtala, oṣu Keji yii, pe ni nnkan bii aago mẹrin aabọ irọlẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejila, oṣu yii, ni awọn aladuugbo kan pe ẹni to ni jẹnẹratọ ọhun, Ọgbẹni Adeṣẹgun Ọnanuga, lori aago, tori oun ko kuku si nile, o ti wa atijẹ atimu rẹ lọ, ni wọn ba ni ko tete maa bọ nile, awọn ti ba a mu ole to fẹẹ ji jẹnẹretọ rẹ gbe nile rẹ to wa laduugbo Ika Ajibẹfun, n’Idi-Ori, nigboro Abẹokuta.

Bi oni-jẹnẹretọ naa ṣe dele lo ba Yusuf Damilare ọhun pẹlu jẹnẹretọ to ji, ati awọn irinṣẹ to fi n tu u, ni gbogbo wọn ba ko rẹi-rẹi lọ si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa Lafẹnwa, wọn si fa a le awọn agbofinro lọwọ.

Wọn lọkunrin naa ti jẹwọ pe loootọ loun jale ọhun, ati pe oun o ṣẹṣẹ maa jale, wọn lo ti n ka boroboro fawọn ọlọpaa nipa awọn ole to ti kopa ninu rẹ sẹyin, ati awọn ẹlẹgbẹ rẹ kan to lawọn jọ n fọle onile kaakiri Abẹokuta ni.

Iwadii ṣi n tẹsiwaju lori iṣẹlẹ yii, lẹyin iwadii ni wọn yoo foju rẹ bale-ẹjọ, gẹgẹ bi Odutọla ṣe wi.

Leave a Reply