Lati kapa awọn agbebọn: Eyi lohun ti Tinubu fẹẹ ṣe

Faith Adebọla

Iṣakoso Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu ti ni kawọn araalu lọọ fọkan balẹ lori ipenija awọn agbebọn ati ajinigbe ti wọn sọ awọn igbo ọba gbogbo di ibuba wọn bayii, tori eto ti fẹẹ pari lati ṣedasilẹ awọn ẹṣọ aṣọgbo to dihamọra gidi, atawọn ologun ti yoo kun wọn lọwọ, lati le gbogbo awọn kọlọransi inu awọn igbo naa jade, ki wọn si maa ṣọ ọ tọsan-toru.

Bakan naa ni ijọba yoo tun ko awọn ẹṣọ alaabo si gbogbo eti okun ati ọsa, atawọn odo nla nla lati le kapa awọn janduku agbebọn to jẹ ori omi lawọn ti n ṣọṣẹ tiwọn.

Agbẹnusọ fun Tinubu lori eto iroyin ati ọgbọn inu, Ọgbẹni Bayọ Ọnanuga, lo sọrọ yii di mimọ lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejila, oṣu Keji ta a wa yii, lasiko to n kopa ninu eto ori tẹlifiṣan ileeṣẹ Arise TV kan.

Ọnanuga ni: “Iṣoro eto aabo jẹ Aarẹ lọkan gidigidi. Tinubu fẹẹ ṣedasilẹ awọn aṣọgbo to kaju-ẹ, ki i ṣe aṣọgbo lasan, bẹẹ lo si fẹẹ ṣeto awọn ẹṣọ alaabo ori omi. Abi ṣe ki i ṣe nnkan itiju pe lorileede ti awọn jagunjagun ori omi wa, ta a lawọn ẹṣọ alaabo sifu difẹnsi ati awọn yooku to yẹ ki wọn maa ṣọ igbo ati awọn odo, sibẹ, niṣẹ nijọba n haaya awọn ajijagbara, awọn ti ki i ṣe oṣiṣẹ ọba, lati pese aabo.

“Ọrọ yii n ka Aarẹ lara o, mo si le sọ ọ fun yin pe laipẹ lẹ maa ri iyatọ, tori Aarẹ ti ṣetan lati gbe awọn igbesẹ yii, a ṣi sọrọ nipa ẹ lọsẹ to kọja yii.

“Mo ro pe Aarẹ kan ṣi n wo awọn nnkan kan daadaa ni, lati ri i pe ko si aleebu ninu erongba naa. Gbogbo eeyan lo mọ pe awọn igbo ọba yii lawọn agbebọn to n jiiyan gbe n lo lati sa pamọ si, ibẹ ni wọn fi ṣe ibuba wọn. Ọna kan ṣoṣo ta a si le gba kapa wọn ni lati ni awọn ẹṣọ tawọn naa dihamọra daadaa lati koju wọn. Awọn aṣọgbo yii ni Aarẹ fẹẹ lo, ohun ta a fẹẹ ṣe niyẹn.”

Ọnanuga lo sọ bẹẹ.

Leave a Reply