Ọlọpaa ti mu awọn gende mẹrin to maa n ja foonu gba l’Ekoo

Adewale Adeoye

Mẹrin lara awọn janduku atawọn alọnilọwọ-gba to n da alaafia ipinlẹ Eko laamu nigba gbogbo lọwọ awọn agbofinro ipinlẹ Eko ti tẹ bayii.

Foonu igbalode lawọn oniṣẹ ibi ọhun jingiri ninu rẹ lati maa ja gba lọwọ awọn araalu nigba gbogbo, ṣugbọn ti ọwọ awọn ọlọpaa tẹ wọn laipẹ yii.

Oniruuru foonu igbalode ni wọn ri gba pada lọwọ awọn gende mẹrin ọhun ti wọn fọwọ ofin gba mu lagbegbe Ilasan, nipinlẹ Eko.

ALAROYE gbọ pe o ti pẹ tawọn gende mẹrin ọhun ti maa n lọ kaakiri agbegbe naa, ti wọn aa si ja foonu gba lọwọ awọn araalu. Ṣugbọn ọwọ palaba wọn ṣegi laipẹ yii, tawọn ọlọpaa si ti fọwọ ofin gba wọn mu. Bakan naa ni awọn agbofinro ọhun tun ri foonu igbalode aimọye gba pada lọwọ awọn oniṣẹ ibi ọhun.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, S.P Benjamin Hundeyin, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejila, oṣu Keji, ọdun 2024 yii, sọ pe awọn maa too ṣewadi nipa awọn gende mẹrin ọhun tawọn aa si foju gbogbo wọn bale-ẹjọ.

Leave a Reply