Nitori ọrọ ti ko to nnkan, iyaale ile yii fọbẹ gun ọrẹ rẹ pa

Adewale Adeoye

Ọdọ awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko niyaale ile kan, Abilekọ Cynthia Aigbondon, to fọbẹ aṣooro  gun ọrẹ rẹ, Oloogbe Basirat Adio, pa lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkanla, oṣu Keji, ọdun yii wa.

ALAROYE gbọ pe nibi tawọn ara agbegbe Ajegunlẹ, nijọba ibilẹ Apapa, nipinlẹ Eko, ti n ṣe waduwadu lati pọn omi ẹrọ ijọba nija kekere kan ti bẹ silẹ laarin oloogbe ọhun ati Abilekọ Cynthia. Ija pe ma a ṣaaju ẹ pọnmi, mi o ni i gba fun ọ, lo dija silẹ laarin awọn iyaale ile meji ọhun. Bi wọn ṣe n bura wọn leebu ara, bẹẹ ni wọn n gbe ọmọ ara wọn ṣepe nla nla. Kawọn eeyan si too mọ ohun to n ṣẹlẹ, Cynthia ti sare wọnu ile lọ, to si lọọ fa ọbẹ aṣooro kan jade ninu kiṣinni rẹ. Gbara to pada de ibi toun ati oloogbe ọhun ti n ja, ṣe lo gbe ọbẹ ọhun le oloogbe nigbaaya, to si gun un yannayanna.

Loju-ẹsẹ ni oloogbe ti mudii lọ silẹ, to si n japoro iku. Nigba ti  Cynthia ri i pe eṣu ti gba ọwọ rẹ lo, lo ba gbiyanju lati sa lọ, ṣugbọn awọn to wa nibẹ gba a mu, ti wọn si fa a le ọlọpaa agbegbe naa lọwọ pe ki wọn ba a ṣẹjọ lori iwa ọdaran to hu ọhun.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, S.P Benjamin Hundeyin, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejila, oṣu Keji, ọdun 2024 yii, sọ pe Ọgbẹni Lukman Adio ti i ṣe ọkọ oloogbe ọhun lo waa fẹjọ sun awọn ọlọpaa ni teṣan awọn kan to sun mọ agbegbe ibi tiṣẹlẹ ọhun ti waye.

Alukoro ni awọn maa too bẹrẹ iwadii nipa isẹlẹ ọhun, tawọn si maa foju afurasi ọdaran yii bale-ẹjọ laipẹ.

 

Leave a Reply