Ọwọ tẹ Ayọmide l’Oṣogbo, waya ile onile lo lọọ ji tu

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ayọmide David Popoọla, ẹni ọdun mejilelọgbọn, lọwọ awọn ọlọpaa ti tẹ niluu Oṣogbo bayii, lori ẹsun igbimọ-pọ jale ati ole jija.

Nnkan bii aago mẹta ọsan ọjọ kẹsan-an, oṣu Keji, ọdun yii, ni ọwọ palaba Ayọmide ṣegi lasiko to n jale lọwọ.

Gẹgẹ bi Igbakeji kọmiṣanna ọlọpaa l’Ọṣun, Hope Okpara, ṣe ṣalaye, awọn eeyan agbegbe Ọṣun GRA, loju ọna Gbọngan, niluu Oṣogbo, ni wọn fi to awọn ọlọpaa leti pe awọn ole kan n ji waya ile kan ti wọn n kọ lọwọ nibẹ.

Ile naa, to jẹ ti Ọgbẹni Akintọla Adebisi Raifu, la gbọ pe Ayọmide atawọn meji mi-in ti tu gbogbo waya ile naa, nigba ti awọn ọlọpaa si debẹ, Ayọ nikan ni wọn ri mu.

O jẹwọ lọdọ awọn agbofinro pe oun ati awọn Hausa meji toun fẹẹ ta awọn waya ti oun ba tu nile onile yii fun lawọn jọ wa sibẹ lọjọ naa, ati pe bi wọn ṣe gburoo awọn ọlọpaa ni wọn juba ehoro.

Ayọmide sọ siwaju pe oun ko mọ ile tabi ibi ti awọn Hausa naa maa n duro si, nitori ọjọ naa gan-an loun ṣẹṣẹ pade wọn.

Okpara sọ pe awọn ọlọpaa ti n lọ kaakiri lati ri awọn to sa lọ naa mu, nigba ti iwadii ba si pari, Ayọmide yoo foju bale-ẹjọ lati sọ ohun to ri lọbẹ to fi waro ọwọ.

 

Leave a Reply