Mi o mọdi tijọba apapọ ṣe fẹẹ gbe ileeṣẹ banki apapọ ile wa ati   FAAN lọ s’Ekoo – Emir Kano

Adewale Adeoye

Emir tilu Kano, Alhaji Aminu Ado Bayero, ti sọ pe bi ebi, iya ati iṣẹ ṣe pọ  laarin ilu ko ṣẹṣẹ bẹrẹ. O ni ki i ṣe asiko ijọba to wa lode bayii ni nnkan bẹrẹ si i dojuru bii ẹsẹ telọ bo ti ṣe wa yii, ṣugbọn o kan legba kan si i lasiko yii ni.

Emir sọrọ naa di mimọ lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejila, oṣu Keji, ọdun 2024 yii, lasiko to n gba iyawo olori orileede yii, Senetọ Olurẹmi Tinubu lalejo laafin rẹ. Alhaji Bayero lo asiko abẹwo iyawo olori orileede yii  lati sọ fun Aarẹ pe awọn araalu n gbe ninu inira gidigidi, o si rọ awọn alaṣẹ ijọba orileede yii lati wa ojutuu sọrọ eto aabo ni kia.

Emir ni ‘Mi o ti i mọ idi tawọn alaṣẹ ijọba orileede yii ṣe fẹẹ fipa gbe ileeṣẹ banki apapọ ile wa CBN ati ileeṣẹ to n ri si igbokegbodo ọkọ baalu FAAN lọ siluu Eko rara.

Loootọ la ni oriṣiiriṣii ọna ta a le gba sọ ẹdun ọkan wa fawọn alaṣẹ ijọba orileede yii, ṣugbọn lara ọna kan gboogi ti Aarẹ fi le gbọ wa ni kiakia ni nipase iyawo rẹ, pe ilu ko fararọ mọ rara.

Loootọ ki i ṣe asiko ijọba yii ni nnkan bẹrẹ si i dojuru, o kan lekenka  si i lasiko yii ni, o si yẹ kijọba tete wa nnkan ṣe si i ko too bọ sori patapata.

Ọrọ nipa eto aabo tun ṣe pataki laarin ilu , loootọ gbogbo wahala ọhun ti wa nilẹ tẹlẹ ko too di pe wọn gbajọba lọwọ awọn ti iṣaaju, ṣugbọn wọn gbọdọ gbaju mọ ọrọ ọhun bayii gidigidi.

Oniruuru ahesọ la n gbọ lati ẹnu awọn araalu nipa bi wọn ṣe fẹẹ gbe awọn ileeṣẹ meji to ṣe pataki ju lọ lorileede yii lọ siluu Eko. Ijọba gbọdọ bọ sita gbangba lati sọ ibi ti wọn n lọ lori ọrọ ọhun, kawọn eeyan le mọ igbesẹ ti wọn maa gbe. Emi paapaa n ko le sọ irufẹ igbesẹ tawọn alaṣẹ ijọba orileede yii fẹẹ gbe lori ọrọ ọhun, bẹẹ ko yẹ ko ṣokunkun si iru emi yii rara. O yẹ ki wọn sọ idi pataki ti wọn ṣe fẹẹ gbe ileeṣẹ meji ọhun lọ siluu Eko lojiji faraalu ni.

 

Leave a Reply