Adeleke gbe igbimọ kalẹ lati yanju wahala ẹgbẹ oṣiṣẹ kootu ati adajọ agba l’Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Lẹyin nnkan bii oṣu mẹta ti agbarijọ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ kootu nipinlẹ Ọṣun ti wa lẹnu iyanṣẹlodi, Gomina Ademọla Adeleke ti gbe igbimọ kan kalẹ bayii lati yanju wahala naa.

Ni bayii, atẹjade kan latọdọ Agbẹnusọ fun gomina, Mallam Ọlawale Rasheed, ṣalaye pe Adeleke ti kọ lẹta si adajọ agba l’Ọṣun ati adajọ agba lorileede yii, nipa erongba rẹ lati wa ojutuu si ọrọ iyanṣẹlodi naa.

O ni igbimọ ọhun, eyi ti Akọwe funjọba ipinlẹ Ọṣun, Alhaji Teslim Igbalaye, yoo jẹ alaga rẹ, ni yoo ṣayẹwo oniruuru ẹsun ti awọn oṣiṣẹ naa fi kan Onidaajọ Adepele, ti wọn yoo si dabaa awọn ọna abayọ fun gomina.

 Tẹ o ba gbagbe, ogunjọ, oṣu Kọkanla, ọdun 2023, ni wahala naa bẹrẹ, nigba ti awọn oṣiṣẹ ọhun tu sita lati fẹhonu han si iwa fa-mi-lete-n-tutọ ti Adajọ agba l’Ọṣun, Onidaajọ Adepele Ojo, n hu si wọn.

Alaga wọn nigba naa, Ọgbẹni Gbenga Eludire, ṣalaye pe gbogbo ọna lawọn gba lati jẹ ki adajọ agba ri inira ti awọn n la kọja, sibẹ, iwa ko-kan-mi lobinrin naa n hu.

Eludire ṣalaye pe lọdun mẹta sẹyin ni Adepele sọ pe ki awọn oṣiṣẹ kan lọọ rọọkun nile lai gbọ awijare lẹnu wọn, o ni ile-ẹjọ tun da awọn kan lare lara wọn, sibẹ, Adepele Ojo ko gba wọn pada sẹnu iṣẹ.

Ọkunrin yii ni awọn kan ti ku lara awọn ti Adepele da duro lai nidii yii, nitori ko si abuja kankan lọrun ọpẹ fun wọn ju owo-oṣu ti wọn n gba yii lọ.

O ṣalaye pe lati ọdun 2016, ni ko ti fun ẹnikẹni laaye lara awọn oṣiṣẹ kootu lati lọ fun ifimọ-kunmọ lẹnu iṣẹ wọn, eleyii ti ko ri bẹẹ tẹlẹ.

Eludire ni ọdọọdun nijọba maa n san owo ajẹmọnu fun aṣọ rira, iyẹn (wardrobe allowance) sinu asunwọn kootu, sibẹ Adepele ko fun awọn oṣiṣẹ lowo yii lati ọdun 2021.

Ọjọ kẹta ti wọn bẹrẹ ifẹhonu han yii ni awọn ọlọpaa yin gaasi tajutaju lati fi tu wọn kan, ibinu yii lo si mu wọn bẹrẹ iyanṣẹlodi ọlọjọ gbọọrọ.

Ṣugbọn latari ewu nla ati wahala ti iyanṣẹlodi naa ni lori awọn araalu lo mu ki awọn ajafẹtọọ ọmọniyan, awọn ọlọpaa, to fi mọ awọn ẹgbẹ oṣelu loriṣiiriṣii maa fọnrere pe ki ijọba gbe igbesẹ lori ẹ.

 

 

Leave a Reply