Iwa palapala, inu ṣọọṣi ni tọkọ-taya yii ti n ṣe ‘kinni’ funra wọn tọwọ fi tẹ wọn

Adewale Adeoye

Ileeṣẹ ọlọpaa agbegbe Maiduguri, lawọn ti fọwọ ofin mu awọn tọkọ-taya meji kan, Abilekọ Khadija Adam, to n gbe lagbegbe Ngomari, ati Ọgbẹni Kaka Ali Umar, to n gbe lagbegbe Damboa, niluu Maiduguri yii kan naa lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkanla, oṣu Keji, ọdun 2024 yii, lasiko tawọn mejeeji n bara wọn sun ninu ṣọọṣi kan ti wọn pe ni ‘All Saints Protestant Church’, to wa ninu ọgba ileeṣẹ ọlọpaa Maiduguri.

ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago mejila ku ogun iṣẹju ọjọ Aje yii, lawọn ololufẹ meji ọhun bẹrẹ si i bara wọn sun ninu ṣọọṣi ọhun. Ariwo buruku tawọn mejeeji n pa lasiko ti wọn n ṣe yunkẹyunkẹ lọwọ lo mu ki oluṣọ agba ijọ ọhun, Ẹni-ọwọ Danjuma Adamu, yọju sibi ti wọn wa lati wo ohun tawọn tọkọ-taya naa n ṣe ti ariwo fi gbalẹ kan to bẹẹ. Ṣe lẹnu ya a gidi nigba to ri awọn mejeeji nihooho ọmọluabi, ti wọn n laagun kikan kikan lori ara wọn.

Loju-ẹsẹ ni wọn ti ranṣẹ pe awọn ọlọpaa pe ki wọn waa fọwọ ofin mu wọn.

Lasiko ti wọn n beere ọrọ lọwọ Abilekọ Khadija, lo jẹwọ pe ẹgbẹrun kan Naira lowo ti Ọgbẹni Kaka f’oun lati b’oun sun, ati pe ileri to ṣe f’oun ni pe kiakia loun maa tete ṣetan, ti ẹnikankan ko si ni i mọ si i.

Awọn ọlọpaa agbegbe naa ti ju awọn ololufẹ meji ọhun sahaamọ wọn bayii, ti wọn si sọ pe awọn maa pe wọn lẹjọ lori ohun ti wọn n ṣe ninu ṣọọṣi ọhun.

 

Leave a Reply