O ma ṣe o, bureeki ọkọ Dyna feeli, lo ba lọọ tẹ ọlọkada pa n’llọrin 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

L’ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejila, oṣu Keji yii, ni ọlọkada kan pade iku ojiji, ti ero meji to gbe ṣẹyin si fara pa yannayanna nibi ijamba ọkọ kan to waye nikorita pipeline, lagbegbe Ọffa garage, niluu Ilọrin.

Ọkan lara awọn olugbe agbegbe naa ti iṣẹlẹ yii ṣoju ẹ, Wasiu Ọlamilekan, ṣalaye pe irọlẹ, ọjọ Aje, Mọnde, ọṣẹ yii, niṣẹlẹ buruku naa waye nibi ti bireeki ọkọ Dyna kan ti feeli, to si lọọ kọ lu ọlọkada tiyẹn gbe ero meji ṣẹyin, to n lọ jẹẹjẹ rẹ. Oju-ẹṣẹ ni ọlọkada ọhun ku, tawọn ero meji to gbe si fara pa yannayanna.

Ọkan lara awọn oṣiṣẹ ajọ to n dari ọkọ loju popo ni Kwara, Kwara State Traffic Management Authority (KWATMA), Ọgbẹni Abdul Ayinde, ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ fidi ẹ mulẹ fun ALAROYE pe ijanu ọkọ Dyna ọhun lo ja, eyi to ṣokunfa ijamba buruku to gba omije loju ẹni ọhun. O ni ọlọkada padanu ẹmi rẹ sinu ijamba ọhun, tawọn ero meji to gbe si fara pa kọja sisọ.

A gbọ pe wọn ti gbe awọn to fara pa lọ sileewosan fun itọju to peye, ti wọn si ti gbe oku ọlọkada lọ si yara igbokuu-si nileewosan ti wọn ko darukọ fun akọroyin wa.

Leave a Reply