Awọn ara Igbajọ yari fun Adeleke, wọn niluu ko le ṣoro ọba lẹẹmeji

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Awọn ile ọlọmọọba Ọwa Oke-Ode atawọn afọbajẹ niluu Igbajọ, nipinlẹ Ọṣun, ti sọ pe ko ṣee ṣe fawọn lati bẹrẹ igbesẹ yiyan Ọwa tuntun, nitori o lodi si iṣẹdalẹ ilu naa lati ṣoro ọba lẹẹmeji.

Nibi ipade oniroyin kan ti wọn ṣe niluu Oṣogbo, ni awọn eeyan ilu ọhun ti fi oju láìfí wo aṣẹ ti Gomina Ademọla Adeleke pa laipẹ yii pe oun fagi le iyansipo Ọba Adegboyega Famọdun, ati pe ki wọn ṣẹṣẹ lọọ bẹrẹ iyansipo ẹni ti yoo jẹ ọba ilu naa.

Gbogbo wọn ni wọn fẹnu ko pe igbesẹ ijọba ọhun lodi si aṣa ati iṣe ilu ọhun, wọn si ke si Gomina Adeleke lati ma ṣe da wahala silẹ ninu ilu Igbajọ.

Wọn ṣalaye pe marun-un ninu awọn afọbajẹ mẹfa ti wọn ni niluu naa ni wọn fọwọ si yiyan Ọba Philip Adegboyega Famọdun gẹgẹ bii Ọwa ti Igbajọ, lọjọ kejilelogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2022.

Wọn ṣalaye pe gbogbo ilana aatẹle ni wọn tẹle nibamu pẹlu ofin ọba yiyan, bẹrẹ lati inu ile ọlọmọọba, titi de ọdọ awọn afọbajẹ, lọ si ijọba ibilẹ, titi de ijọba ipinlẹ, ko too wa di pe wọn kede rẹ, ti wọn si yan an lọba tilu-tifọn.

Gẹgẹ bi wọn ṣe wi, ”Aṣa yiyan Ọwa ilu Igbajọ ko ṣee bẹrẹ lakọtun, nitori wọn ki i ṣe etutu rẹ lẹẹmeji. Gbogbo awọn ọmọọba ti inu n bi ti wa ni kootu lati pe iyansipo Ọba Philip Adegboyega Famodun lẹjọ pẹlu iwe ipẹjọ to ni nọmba HIK/1/2023. Ọmọọba Ọlaniyi Akande atawọn yooku ni wọn gbe gomina ipinlẹ Ọṣun atawọn miiran lọ si kootu.

“A n rọ ijọba lati ma ṣe da omi alaafia ti ilu wa ti n jẹgbadun rẹ latọdun pipẹ ru, iṣẹdalẹ ilu Igbajọ ṣe iyebiye pupọ, ti ẹnikẹni ko gbọdọ kọwọ bọ.

‘’A mọ pe ẹṣẹ kan ṣoṣo ti Ọba Famọdun ṣẹ ijọba yii ni pe o jẹ alaga tẹlẹ fun ẹgbẹ oṣelu APC l’Ọṣun, ṣugbọn ọrọ oṣelu ko kan iṣẹdalẹ wa, ẹni ti ifa ba ti mu ni’’

‘Awa o le tun ọba miiran yan mọ o, tori bi ọba kan ko ba ku, a ki i fi ọba miiran jẹ niluu Igbajọ. Ọrọ wa wa nile-ẹjọ, ki gomina yọnda kootu lati dajọ’

 

Leave a Reply