Aara san pa agbabọọlu yii lasiko to n gba bọọlu lọwọ

Adewale Adeoye

Ṣe lọrọ ọhun di bo o lọ yago fun mi lasiko ti aara buruku kan san lojiji, to si pa agbabọọlu kan, Oloogbe Septain Raharja, to n gba bọọlu lọwọ ni papa iṣere nla ti Siliwangi, to wa lagbegbe West-Java, lorileede Indonesia, lọhun-un.

ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago mẹrin kọja ogun iṣẹju lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹwaa, oṣu Keji, ọdun 2024 yii, ni oloogbe naa n gba bọọlu fun ẹgbẹ agbabọọlu rẹ ti won n pe ni Subang, lorileede naa. Idije bọọlu ọlọrẹẹ-ṣọrẹẹ kan lo n kopa ninu rẹ lọwọ, lojiji ni oloogbe ọhun to jẹ ẹni ọdun marundinlogoji ṣubu lulẹ gbalaja lẹyin ti aara buruku ọhun san pa a. Ṣe lawọn ẹgbẹ rẹ gbogbo sa wọgbẹ lọ ni ni gbara ti iṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ.

Awọn ti iṣẹlẹ ọhun ṣoju wọn sọ pe ki i ṣe loju-ẹsẹ ti aara ọhun san lo pa oloogbe ọhun, wọn ni o to nnkan bii wakati kan lẹyin ti aara ọhun san ti ko rẹni kankan to maa sun mọ lo too ku.

Awọn alaṣẹ ijọba orileede ọhun ti ni ọrọ aara sisan pa awọn agbabọọlu orileede ọhun ti fẹẹ maa di gbogbo igba bayii, nitori pe lọdun to kọja yii ni aara buruku kan san pa agbabọọlu ọmọ orileede naa kan lasiko idije pataki ti wọn ṣe laarin ilu naa, loju-ẹsẹ tiẹ ni agbabọọlu naa tọjọ ori rẹ ko ju  ọdun mẹtala lọ ku ni tiẹ lẹyin ti ara ọhun san pa a tan.

 

Leave a Reply