Nitori bi nnkan ṣe gbowo lori, eyi niye owo-oṣu ti ẹgbẹ oṣiṣẹ fẹ kijọba apapọ maa san

Adewale Adeoye

Nitori ojojo to n ṣe ọrọ aje orileede wa, eyi to mu ki gbogbo nnkan gbẹnu soke, tawọn alaṣẹ ijọba orileede yii ko si ri ohun gidi kan ṣe si i,  ẹgbẹ oṣiṣẹ lorileede yii, ‘Nigeria Labour Congress’ (NLC), ti ni o ṣee ṣe kawọn beere to miliọnu kan Naira lọwọ  ijọba apapọ gẹgẹ bii owo-oṣu tawọn maa gba.

Aarẹ ajọ ọhun, Kọmureedi Joe Ajero, lo sọrọ ọhun di mimọ lasiko to n bawọn oniroyin sọrọ lori bi nnkan ko ṣe fararọ mọ rara faraalu atawọn oṣiṣẹ gbogbo.

Ajero ni, ‘A ṣi n foju ṣunnukun wo ọrọ ọhun ni, bi awọn alaṣẹ ijọba orileede yii ko ba wa wọrọkọ fi ṣada lori bi nnkan ṣe n gbowo lori nigba gbogbo, a maa too beere pe ki ijọba san miliọnu kan Naira fun wa gẹgẹ bii owo oṣu awọn oṣiṣẹ. Ko sẹni ti ko mọ pe lati igba ti olori orileede yii, Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, ti yọwo iranwọ lori epo bẹntiroolu ni gbara to dori aleefa ni gbogbo nnkan ti le ju bo ṣe yẹ lọ’.

Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja yii, ni ajọ oṣiṣẹ ati ẹgbẹ awọn ọlọja ‘Trade Union Congress’ (TUC) ṣepade pajawiri kan laarin ara wọn, ti wọn si fẹnu ko pe awọn fun ijọba orileede yii ni gbedeke ọjọ mẹrinla pere lati fi wa ojutuu si bi nnkan ṣe ri lorileede yii, paapaa ju lọ, bi ounjẹ ṣe gbowo lori kọja afẹnusọ laarin ilu.

Atẹjade kan ti wọn fi sita lẹyin ipade wọn ni wọn lawọn ti fajuro gidi lori bi ijọba apapọ ko ṣe ṣiika adehun to wa laarin awọn nibi ipade pajawiri kan to waye laarin awọn atijọba loṣu Kẹwaa, ọdun 2023, pe ki wọn wa nnkan ṣe si bawọn araalu ṣe n jiya.

Leave a Reply