Ijọba gba ọkada rẹpẹtẹ nidii awọn ọlọkada niluu Eko, eyi lohun ti wọn fi i ṣe

Adewale Adeoye

Ni bayii,  ijọba ipinlẹ Eko ti lawọn ko ni i fọwọ yọbọkẹ mu ọrọ awọn ọlọkada gbogbo ti wọn joye aleti-lapa, ti wọn faake kọri, ti wọn ṣi n gbero lawọn ojuna marosẹ gbogbo tijọba ti la kalẹ gẹgẹ bii ẹẹwọ fun wọn lati maa gbe ọkada wọn gba.

Aipẹ yii ni ẹka ajọ amunifọba to n gbogun ti iwa aigbọran ati titẹ ofin loju laarin ilu Eko, ‘Lagos State Task Force’, lọ soju ọna marosẹ Eko si Badagary, ti wọn si gba ọkada to to mẹtadinlẹẹẹdẹgbẹta(497) lọwọ awọn ọlọkada to n fi  wọn ṣiṣẹ lawọn ojuna tijọba Eko ti fofin de pe wọn ko gbọdọ de.

Ọga agba ajọ Tasks-force ọhun, C.S.P Shola Jẹjẹloye, lo ṣaaju ikọ kan lọ sawọn agbegbe bii, Igbo-Elerin, ibudokọ Doyin, Iyan-Iba, Akakija atawọn agbegbe gbogbo to sun mọ awọn ibi ta a darukọ wọnyi.

Ninu ọrọ rẹ lori igbesẹ ọhun ni Jẹjẹloye ti sọ pe awọn gbe igbesẹ ọhun ni ibamu pẹlu ofin irinna ilu Eko, tawọn si gbọdọ ri i daju pe gbogbo araalu pata lo tẹle e.

Lopin ohun gbogbo, Jẹjẹloye rọ awọn araalu, paapaa ju lọ awọn ọlọkada, pe ki wọn bọwọ fun ofin ati ilana irinna ọkọ niluu Eko, ki wọn ma ṣe gbe ọkada wọn soju titi marosẹ tawọn alaṣẹ ijọba ipinlẹ Eko ti fofin de, ki wọn ma baa jẹbi iwa aibikita wọn.

Leave a Reply