Ewu nla n rọ dẹdẹ lori Naijiria pẹlu bi wọn o ṣe fi Sunday Igboho silẹ yii- Ẹgbẹ Oodua Worldwide  

Faith Adebọla

Ẹgbẹ ajijagbara awọn ọmọ Yoruba to wa lẹyin odi, Oodua Worldwide, ti kede pe niṣe ni atimọle ti wọn fi Oloye Sunday Adeyẹmọ tawọn eeyan mọ si Sunday Igboho, si lorileede Olominira Bẹnẹ mu ki Naijiria wa ninu ewu, gudugbẹ si le ja bi wọn ko ba tete fi ọkunrin naa silẹ.

Ninu atẹjade kan ti ẹgbẹ naa fi lede lati orileede Canada, Aarẹ ẹgbẹ ọhun, Adewale Ojo, sọ pe gbogbo ohun to ba gba lawọn maa fun lati ri i pe wọn tete tu Sunday Igboho silẹ lahaamọ.

Ojo ni: “Titu Sunday Igboho silẹ lai fakoko ṣofo nikan loun to le rọ awọn eeyan tinu n bi sijọba yii lọkan, tori o ti foju han pe ijọba aṣetinu-ẹni to n fi ẹya kan ṣọga lori ẹya mi-in ni wọn.

Bawọn eeyan pataki pataki ṣe da si ọrọ Sunday Igboho lahaamọ to wa, ti ọpọ n lọọ ṣabẹwo si i ni Bẹnẹ lati ṣatilẹyin ati koriya fun un ti fihan gbangba pe wọn nifẹẹ si bọkunrin naa ṣe n ja nitori awọn eeyan rẹ, wọn mọ pe abosi ati ojuṣaaju tijọba n ṣe ninu iṣejọba Naijiria lasiko yii nilo ayipada gidi, tori nnkan o le maa lọ bayii ko rọgbọ.”

Ẹgbẹ naa tun bẹnu atẹ lu bijọba ṣe fari apa kan da ọkan si latari bi wọn ṣe fi awọn mẹjọ silẹ ninu awọn ọmọ ẹyin Sunday Igboho tawọn ẹṣọ ọtẹlẹmuyẹ DSS mu sahaamọ silẹ, ti wọn tun da awọn mẹrin to ku pada satimọle.

“A n beere pe ki wọn yaa fi Sunday Igboho silẹ lai fa ọrọ gun mọ, ati awọn eeyan ẹ ti wọn da pada sahaamọ, ti wọn ba fẹ ki ewu to n rọ dẹdẹ lori Naijiria yii dawọ duro. Ko i tii ye wa bi awọn to n ni ilu lara ni Naijiria ṣe n rin ti wọn n yan fanda kiri, ṣugbọn ti wọn mu awọn to n ja fun aabo ati ẹtọ wọn satimọle.

Ọna kan ṣoṣo to wa lati jẹ ki alaafia ati ibalẹ ọkan jọba ni Naijiria ni kijọba apapọ gbe igbesẹ to maa mu kawọn eeyan nireti pe igba ọtun tootọ ati ayipada rere ṣi ṣee ṣe, aijẹ bẹẹ, ajalu ati ewu ni wọn n kọwe si.

Leave a Reply