Ẹya yoowu to ba fẹẹ yapa kuro ni Naijiria n wa iparun ni-Pasitọ Iyunade

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Olori ijọ Pentecostal Sanctuary Bible Ministries (PSBM) Odo-Ẹgbọ, n’Ijebu Ode, Pasitọ Sunday Dare Iyunade, ti sọ pe ẹya yoowu to ba gbe igbesẹ lati yapa kuro lara Naijiria yoo parun ni, nitori Ọlọrun ko fọwọ si igbesẹ bẹẹ.

‘Ọlọrun sọ pe bi ẹyakẹya, boya Igbo, Yoruba tabi Hausa, ba gbiyanju lati kuro lara Naijiria, ibi ti wọn fi ṣe ibugbe yoo di itan ni’’ Bẹẹ ni Pasitọ Iyunade wi fawọn akọroyin lọsẹ to kọja yii.

Pasitọ yii sọ pe eyi tawọn eeyan kan fi n beere fun ipinya yii, adura lo yẹ ki wọn maa gba si i kikankikan, pe ki orilẹ-ede yii ma pin, o ni nitori ipinya yoo mu abamọ ati iṣoro wa ni.

Ni ti ẹgbẹ oṣelu All Progressives Party (APC) to n ṣejọba lọwọ, Pasitọ Iyunade sọ pe o ṣee ṣe kawọn ọmọ Naijiria sọ wọn loko laipẹ lati le wọn kuro lori aleefa, gẹgẹ bawọn funra wọn ṣe wi nigba ti wọn n polongo ibo lọdun 2014, pe bawọn ko ba ṣe daadaa, kawọn ọmọ Naijiria le awọn loko.

Lori idi ti eyi yoo fi ri bẹẹ, Olori ijọ PSMB naa sọ pe gbogbo ileri tawọn APC ṣe faraalu nigba naa ni wọn ti kọyin si, ti wọn ko mu wọn ṣẹ rara. O tẹsiwaju pe Ọlọrun ti tilẹkun mọ ijọba Buhari, idi niyẹn ti wọn ko fi ri aṣeyọri ṣe, o ni bawọn Kristẹni ko ba tẹpẹlẹ mọ adura, nnkan yoo wulẹ maa le si i ni.

Eto aabo to dojuru naa wa ninu ohun ti pasitọ yii ṣalaye, Iyunade sọ pe ogiri aabo ti wo lulẹ ni Naijiria, ṣugbọn o ni kawọn eeyan ma sọ ireti nu, nitori Oluwa ti sọ pe oun yoo fi opin si iṣejọba APC laipẹ, ijọba tuntun ti yoo laaanu awọn eeyan rẹ yoo de, ẹni ti yoo jẹ loun ko le sọ.

Leave a Reply