Eyi lohun tawọn aafaa Ilọrin tun ṣe fun Ta-ni-Ọlọhun

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

L’Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹfa, oṣu Keji yii, ni idunu ṣubu layọ fun gbajumọ oniṣẹṣe nni, AbdulAzeez Adegbọla, ti gbogbo eeyan mọ si Ta-ni-Ọlọrun, pẹlu bi Aafa Labeeb Lagbaji ati Mọdrasat Muhammad ṣe wọgi le ẹjọ ti wọn pe e sile-ẹjọ Majisireeti to fikalẹ siluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara, wọn ni awọn o ba a ṣẹjọ mọ.

Eyi waye latari igbeṣẹ ti awọn olupẹjọ gbe nipasẹ awọn agbẹjọro wọn, wọn ni awọn ti fọwọ wọnu, awọn ko ṣẹjọ pẹlu Ta-ni-Ọlọrun mọ, ni adajọ ba fagi le ẹjọ naa.

Ẹsun ọtọọtọ ni awọn mejeeji fi kan an nile-ẹjọ kan naa, niluu Ilọrin. Ẹsun ibanilorukọjẹ ni Labeeb Lagbaji fi kan Ta-ni-Ọlọrun, nigba ti Mọdrasat Muhammad, fẹsun jijo Kurani nina kan an.

Agbẹjọro awọn mejeeji lo sọ fun ile-ẹjọ pe awọn olupẹjọ ni awọn ti ṣetan lati wọgi le ẹjọ ti awọn pe, awọn ko ṣẹjọ mọ. Wọn ni onibaara awọn ṣe ipinnu yii latari ipade alaafia kan to waye laarin wọn ati olujẹjọ.

Onidaajọ Mohammed Adam, ti wọgi le ẹjọ ọhun, lo ba ni ki Ta-ni-Ọlọrun maa lọ layọ ati alaafia.

Leave a Reply