Tanka jona gburugburu, dẹrẹba fara pa, ninu ijamba ina ileepo Bovas, n’llọrin 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Bo tilẹ jẹ pe ko sẹni to ku ninu ijamba ina to ṣẹlẹ nileepo BOVAS, niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, laaarọ kutu Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ keje, oṣu Keji yii, sibẹ, dẹrẹba mọto naa fara pa, bẹẹ ni ori si ko awọn eeyan to wa nileepo ọhun yọ pẹlu bi ọkọ tanka kan ṣe deedee gbina lojiji, lasiko to n ja epo sileepo ọhun to wa lagbegbe Odòotà, l’Opopona Papakọ ofurufu ilu Ilọrin.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Alukoro ileeṣẹ panapana ni Kwara, Hassan Hakeem Adekunle, ni ni nnkan bii aago meje aabọ aarọ kọja diẹ ni ileesẹ panapana gba ipe pajawiri lati agbegbe ọhun pe ileepo Bovas, n jona. O ni nigba tawọn debi iṣẹlẹ naa lawọn ba tanka epo kan to gbe epo lita marundinlaaadọta (45,000 liters of PMS) ti nọmba rẹ jẹ AGG 728XK, to n jona.

Wọn ni niṣe lo gbina lasiko to n ja epo sinu koto nileepo ọhun, ṣugbọn bi ajọ panapana ṣe debẹ ni wọn pa ina naa, ko ma baa ran mọ dukia miiran nitosi ibẹ, nitori pe ina ọhun lagbara, tanka epo ọhun si jona gburugburu.

O tẹsuwaju pe dẹrẹba to wa ọkọ epo ọhun jona diẹ, ṣugbọn oun nigbagbọ pe lẹyin itọju, ara rẹ yoo ya laipẹ.

Ọga ajọ panapana ni Kwara, Ọmọọba Falade John Olumuyiwa, rọ gbogbo olugbe ipinlẹ naa ki wọn maa wa loju ni alakan fi n ṣọri lọfiisi ati ninu ile, ki wọn si maa yago fun gbogbo ohun to le ṣokunfa ijamba ina layiika wọn.

 

Leave a Reply