Faanu inu mọṣalaaṣi lawọn eleyii maa n ji tu, ọwọ ti tẹ wọn

Adewale Adeoye

Awọn agba bọ wọn ni ọjọ gbogbo ni t’ole, ọjọ kan ni t’olohun. bẹẹ gan-an lo ri fawọn jaguda ẹlẹni mẹta kan ti wọn maa n lọ kaakiri aarin ilu Minna, nipinlẹ Niger, ti won yoo si ja ile onile wọle, ti wọn aa ji awọn dukia olowo iyebiye lọ.

Ni bayii, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Niger lawọn ole mẹta kan, Ọgbẹni Mohammed Auwal Abdulsalam, ẹni ọdun mẹrinlelogun, Abdulraheem Abdulsalam, ẹni ọdun mẹrindinlogun, ati Abdullah Usman, ẹni ọdun mẹtadinlogun, ti gbogbo wọn pata n gbe lagbegbe Dutsen-Kura/Gwari, niluu Minna, ipinlẹ Niger, to jẹ pe wọn ti jingiri ninu iṣẹ ole jija wa.

Ẹsun ti awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa fi kan wọn ni pe wọn lọọ jalẹkun mọṣalaaṣi nla Jimoh kan lagbegbe Dutsen-Kura/Kwasau, ti wọn si tu faanu ara ogiri meje lọ nibẹ.

ALAROYE gbọ pe ni Nnkan bii aago mejila ọsan ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2024 yii, ni awọn ole ọhun lẹdi apo pọ lati lọọ ji awọn faanu ọhun ko ni mọṣalaasi nla Jimoh ọhun, ko si pẹ ti wọn ṣiṣẹ buruku ọhun tan ti ọwọ fi tẹ gbogbo wọn lasiko ti wọn fẹ tun ẹru ole naa ta fawon araalu ni gbanjo.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, D.S.P Wasiu Abiọdun, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹfa, oṣu Keji, ọdun yii, ni olu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa sọ pe, ‘Ikọ ọlọpaa kan to n gbogun ti awọn ajinigbe lagbegbe Dutsen-Kura/Shanu, ni wọn n lọ kaakiri agbegbe naa, ti wọn si ri awọn mẹta ọhun pẹlu apo ṣaka lọwọ wọn. Irin ẹsẹ wọn to mu ifura dani ni wọn fi da wọn duro, ti wọn si yẹ inu apo ṣaka ti wọn gbe dani wo. Wọn ba faanu meje tawọn ole ọhun ji ko ninu mọṣalaṣi ọhun lọwọ wọn. Wọn si fọwọ ofin mu gbogbo wọn. Ọdọ awọn ọlọpaa ti wọn wa ni wọn ti jẹwọ pe ninu mọṣalaaṣi lawọn ti ji i ko.

‘Ninu iwadi tawọn agbofinro ṣe ni wọn ti ri ẹri to daju gbangba pe o pẹ diẹ sẹyin bayii tawọn ole ọhun ti maa n lọ kaakiri aarin ilu Minna, ti wọn aa si fọ ile onile wọle, ti wọn maa ji awọn dukia olowo iyebiye lọ.

Alukoro ni awọn maa too foju gbogbo wọn bale-ẹjọ.

 

Leave a Reply