O ma ṣe o, akẹkọọ Fasiti OOU gbẹmi ara rẹ sinu otẹẹli

Adewale Adeoye

Titi di asiko ta a n koroyin yii jọ lọrọ bi Oloogbe Adaeze Doris Jaja, orekelẹwa akẹkọọ ileewe ‘Ọlabisi Ọnabanjọ University’ to wa ni Agọ-Iwoye, nipinlẹ Ogun, ṣe gbe majele jẹ ninu otẹẹli igbalode kan, to si ku loju-ẹsẹ ko too di pe awọn oṣiṣẹ otẹẹli ọhun mọ si i ṣi n ya awọn eeyan lẹnu gidigidi.

ALAROYE gbọ pe iṣẹlẹ laabi ọhun waye lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2024 yii, nile-itura igbalode kan ti wọn n pe ni ‘Be-Happy Hotel’ to wa lagbegbe Agọ-Iwoye.

Ko sẹni to mọ ohun to mu ki akẹkọọ ọhun gbe iru igbesẹ buruku ọhun, to si para ẹ danu lai jẹ ki ẹnikankan mọ nipa rẹ. Koda, ko kọ idi pataki to ṣe gbe igbesẹ ọhun sinu beba gẹgẹ bi ọpọ awọn to ba gbẹmi ara wọn ṣe maa n ṣe.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, S.P Ọmọlọla Odutọla, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹfa, oṣu Keji, ọdun 2024 yii, ni olu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ ọhun to wa ni Eleweeran, l’Abẹokuta, sọ pe, ‘Ọnarebu Ọduniyi Adelaja lo lọ si teṣan ọlọpaa agbegbe naa ni nnkan bii aago mẹfa owurọ kutukutu ọjọ ti iṣẹlẹ ọhun waye, to si ṣalaye pe Ọgbẹni Adebayọ Israel, ti i ṣe ọkan lara awọn oṣiṣẹ otẹẹli ọhun lo pe oun lori foonu, to si ṣalaye nipa iṣẹlẹ ọhun f’oun. Pe oloogbe  to jẹ akẹkọọ ileewe Fasiti Ọlabisi Ọnabanjọ gbe majele jẹ ninu iyara to gba ni otẹẹli ọhun. DPO teṣan agbegbe ọhun lo ran awọn ọmọọṣẹ rẹ lọ lati lọọ wo ohun to n ṣẹlẹ, wọn ba oku oloogbe ọhun nilẹ, ti wọn si ba amuku ati ike ti majele to fi gbẹmi ara rẹ ọhun wa lẹgbẹẹ rẹ nilẹẹlẹ nibẹ.

Loju-ẹsẹ tawọn ọlọpaa ọhun debẹ ni wọn ti sare gbe e lọ sileewosan kan ti wọn n pe ni ‘Best Care Hospital, ṣugbọn won ko gba a lọwọ wọn. Wọn tun gbe e digbadigba lọ sileewosan ‘Love and Care’, niluu Agọ-Iwoye, nibẹ lawọn dọkitato ṣayẹwo fun un ti sọ pe oku oloogbe ọhun ni wọn gbe wa sileewosan awọn.

Alukoro ni wọn ti gbe oku akẹkọọ ọhun lọ si mọṣuari ileewesan ‘Ọlabisi Onabanjọ University’, fun ayẹwo lati mọ ohun to ṣeku pa a mọ’nu otẹẹli ọhun.

Leave a Reply