Usman ṣa ọlọkada ladaa yannayanna, lo ba ji ọkada rẹ gbe sa lọ 

Adewale Adeoye

Ọdọ awọn ipinlẹ Niger ni gende kan torukọ rẹ n jẹ Usman Maniya, ẹni ọdun mejilelogun, to n gbe lagbegbe Gbete, wa bayii. Ẹsun iwa ọdaran ni wọn fi kan an laipẹ yii. Wọn ni o fada ṣa ọlọkada kan yannayanna, o si ji ọkada rẹ gbe sa lọ ko too di pe ọwọ tẹ ẹ laipẹ yii.

ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago mọkanla owurọ kutukutu ọjọ kejilelogun, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2024 yii, ni Usman pe ọlọkada kan pe ko waa gbe oun lọ sibi kan. Wọn jọọ dunaa-dura tan, bi ọlọkada ọhun ṣe n gbe e lọ sibi ti Usman juwe fun un lo ba yọ ada oloju meji si i lojiji, o si bẹrẹ si i ṣa ọkunrin naa bii ẹni to n ṣa maaluu. Niṣe lo bu u ladaa lọwọ ati ni gbogbo ara rẹ. Lẹyin naa lo ji ọkada rẹ gbe sa lọ. Ṣugbọn ọwọ awọn agbofinro pada tẹ ẹ laipẹ yii.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, D.S.P. Wasiu Abiọdun, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹfa, oṣu Keji, ọdun 2024 yii, ni olu ileeṣẹ ọlọpaa ipinle ọhun sọ pe lẹyin ti Usman ji ọkada ọhun gba tan lawọn ọlọpaa teṣan Kudu, niluu Mokwa, gba ipe pajawiri kan pe oniṣẹ ibi kan ti ji ọkada ọlọkada gbe sa lọ. Wọn bẹrẹ  iwadi nipa iṣẹlẹ ọhun, wọn si fọwọ ofin mu Usman to ji ọkada gbe nibi to sa pamọ si.

Wọn ri ada oloju meji kan ti afurasi ọdaran yii lo lati fi ṣiṣẹ ibi ọhun lọwọ rẹ,  wọn si ti ju ọmọkunrin naa sahaamọ  ọlọpaa fun iwadii nipa ohun to ṣe yii.

Ọlọkada ti Usman ṣa yannayanna n gba itọju lọwọ nileewosan ijọba agbegbe naa ti wọn n pe ni ‘Mokwa General Hospital’.

Alukoro ni awọn maa too foju rẹ bale-ẹjọ ko le fimu kata ofin.

 

 

Leave a Reply