Haa! Baba yii jẹ nnkan eewọ, o ti ha patapata

Adewale Adeoye

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Niger, ni baba agbalagba kan, Adamu Danga, ẹni ọdun mejilelọgọta wa, nnkan eewọ ti ko yẹ ki agbalagba jẹ ni baba naa fi kan ẹnu. Ọmọ ọdun mẹfa pere ni baba naa ki mọlẹ niluu Minna, nipinle Niger lọhun-un, lo ba fipa ba a lo pọ bii ẹni pe agbalagba ni.

ALAROYE gbọ pe aipẹ yii ni Adamu ki ọmọ ọhun mọlẹ nitẹkuu kan, to si fipa ba a lo pọ daadaa. Ṣa o, lasiko to n hu iwa laabi ọhun ni araalu kan ri i, to si figbe bọnu. Loju-ẹsẹ ni Adamu sa lọ, ṣugbọn awọn araalu sa tọ ọ lẹyin, wọn si gba a mu. Wọn fọwọ ba a diẹ ko too di pe wọn fa a le awọn ọlọpaa agbegbe nibi ti iṣẹlẹ ọhun ti waye lọwọ. Lasiko ti wọn n lu u lọwọ ni Adamu jẹwọ pe ẹmu kan toun mu yo lo fa a toun fi ṣiwa-hu lọjọ naa.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, D.S.P. Wasiu Abiọdun, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹfa, oṣu Keji, ọdun yii, sọ pe awọn eeyan agbegbe Bosso, ni wọn fọwọ ofin mu Adamu ni nnkan bii aago mẹfa irọlẹ pe o n fipa ba ọmọdebinrin kan ti ko ju ọdun mẹfa lọ sun nitẹkuu kan to wa lagbegbe naa, wọn mu un, wọn lu u daadaa, ko too di pe wọn fa a le ọlọpaa lọwọ.

Ọdọ awọn agbofinro ni Adamu ti jẹwọ pe loootọ loun fipa mu ọmọde ọhun wọnu itẹ-oku lasiko to n bọ lati ibi ti awọn obi rẹ ran an lọjọ naa.

Alukoro ni baba agbalagba ọhun jẹwọ pe ẹmu kan toun ṣẹṣẹ mu yo lo ṣokunfa b’oun ṣe ṣiwa-hu lọjọ yii.

Wọn ti ju Adamu sahaamọ ọlọpaa to n ri sọrọ awọn ọdaran nipinlẹ naa ki wọn le ṣewadii nipa iṣẹlẹ ọhun.

Leave a Reply