Nitori MC Oluọmọ, awọn ẹgbẹ onimọto Eko kọju ija si Wasiu Ayinde 

Monisọla Saka

Ọkan pataki lara awọn ọmọ ẹgbẹ onimọto National, iyẹn National Union of Road Transport Workers (NURTW), ẹka ti Isọlọ/Ejigbo, nipinlẹ Eko, Ọgbẹni Abayọmi Oluṣẹgun, ti inagijẹ ẹ n jẹ Yọmi Poly, ti sọrọ lai ṣẹkan ku, lori ẹni to n da omi alaafia ẹgbẹ naa ru nipinlẹ Eko.

Yọmi ti waa rawọ ẹbẹ si Gomina Sanwo-Olu lati ba wọn wa nnkan ṣe si i, ko ma si ṣe gba fun olorin kan to n gbe niluu Ijẹbu, lati maa fọwọ lalẹ lori bi eto gbogbo yoo ṣe maa lọ ninu ẹgbẹ wọn l’Ekoo. O naka aleebu si Wasiu Ayinde Marshal, gẹgẹ bii alabosi eeyan, ati eku ẹda to da gbogbo rẹ silẹ.

Bẹẹ lo tun fun gbajumọ oṣere tiata nni, Ẹbun Oloyede, tawọn eeyan mọ si Ọlaiye Igwe, ni abuku to tọ si i, o ni awọn alabosi ti wọn da gbogbo ori ọrọ ru, ti wọn wa n wa oju rere araalu pada niyẹn.

Ninu fọnran kan to ṣe, to gbe sori ayelujara lo ti ni, “Ẹ kaaarọ, ẹ kaasan, ẹ kaalẹ o. Orukọ mi ni Abayọmi Oluṣẹgun, tawọn eeyan mọ si Yọmi Poly. Ẹ jọọ, Gomina Sanwo-Olu, ẹ jọọ, ẹ dide, ẹ jọọ, ẹ ba wa da sọrọ iṣẹ wa yii. Ọjọ kọkanlelọgbọn, ipari oṣu to lọ, ni Alaaji Musiliu Akinsanya (MC Oluọmọ) da ni ọdọ yin ni Alausa nibẹ yẹn, wọn dẹ fa ọwọ Mustapha Ajagungbade (Baba Ebute), soke pe oun ni ‘next state chairman’, pe awọn MC n lọ si Abuja, a dẹẹ fẹ sin wọn lọ s’Abuja.

Gbogbo nnkan ti to, awọn ọga wa ti ṣepade pẹlu wọn, wọn ti waa sọ fun wa nile pe gbogbo nnkan ti wa ni iṣọkan, latigba yẹn, ẹ o ri fidio kankan o, tabi pe ẹni kan n kun ni kọ̀rọ̀.

“Aṣe awọn ẹni kan wa ninu Eko yii, wọn wa n’Ijẹbu, wọn dẹ n nawọ sinu Eko. Ẹyin gomina, ẹ n paṣẹ, awọn naa tun n paṣẹ. Mi o riru ẹ ri laye mi, ki gomina paṣẹ, ki olorin tun maa paṣẹ n’Ijẹbu. Bẹ ẹ ṣe ṣe titi naa niyẹn, ibudo idibo yin niyẹn ni Ọkọta/Isọlọ, ṣe ẹ jawe olubori nibẹ ri ni? Ẹ o gbegba oroke nibẹ ri. Ẹ ṣẹṣẹ maa pe wa ni. Ẹ wa n ṣe fidio pe Aarẹ o, igba o, àwo o, ina o daa, gbogbo nnkan ko daa. Ṣe o gba ẹnu yin? Ilu o daa, a ni ka tun un ṣe lati aidaa si eyi to daa, ẹ o gbọ.

Ẹyin gangan ni ẹ tun wa ninu kọrọ yẹn tẹ ẹ n ba a jẹ, ẹyin lẹ wa ninu okunkun tẹ ẹ n tafa sinu imọlẹ.

“Eeyan ṣe nnkan ti ko daa, ọdun mẹrin ni eeyan fi ṣe kiateka (caretaker), Alaaji Musiliu Akinsanya ṣe caretaker fun ọdun mẹrin, wọn ko gbogbo owo lọ. Igba to jẹ pe gbogbo owo yẹn naa, ẹyin ni wọn wa n na an fun loju agbo. Ẹyin ni wọn n nawo yẹn fun loju agbo.

“Mi o mọ ibi ti olorin ti tun n yan onilu tabi ẹni to n ba a ṣawo to n fun un ni slot, mi o riru ẹ ri, ori yin lo ti bẹrẹ. Ẹ o jẹ ka jẹ nibẹ, ẹ o jẹ ka mi. Gbogbo awa ẹgbẹ National Union, a o rowo jẹun, ẹyin ni wọn n kowo wa fun. Ẹ waa bọ sita, ẹ n ṣe fidio ipade tẹ ẹ ṣe. Ẹ wa n sunkun lori stage, ti wọn ba ni ta ni ẹni akọkọ to n da Eko ru, ẹyin lo yẹ ki wọn mu, ni apa South West (Guusu Iwọ Oorun) yii gan, ẹyin lo yẹ ki wọn mu.

“Gbogbo ibi ni ẹ ti fẹ maa paṣẹ, Alaaji Wasiu Ayinde. Ẹ o duro lori iyẹn, Ọlaiya Igwe naa fiṣẹ ẹ silẹ, ṣe wọn ran ẹ niṣẹ ni?

Ẹyin naa ṣe fidio pe ẹ kabaamọ pe ẹ tẹle Tinubu. Ṣe ibo yin lo gbe Tinubu wọle? Ọlaiya Igwe, mo ni ṣe ibo yin lo mu Tinubu wọle? Ẹ jọọ, ṣe bi ẹyin n ṣe ka ri mi ni, oun ni ẹ ṣe lọ si okun.

Ẹ o tilẹ dupẹ pe okun o gbe yin lọ. O yẹ ki okun yẹn gbe yin lọ ni, nitori nnkan ti ko denu ni ẹ lọọ ṣe. Nnkan oṣi ni ẹ lọọ ṣe. Funra ara yin lẹ ṣe e, ẹ o ṣe e nitori ilọsiwaju ati igbega orilẹ-ede yii. Ẹ ṣe e nitori pe Musiliu Akinsanya n kowo jẹ fun ọdun mẹrin, nitori bẹẹ ni ẹ ṣe lọọ ṣe e, ki i ṣe nitori ẹnikankan.

Alaaji, ni Raddison Blu, ẹ pe wa sipade ni gbogbo Isọlọ/Ejigbo, ẹ n fibọn bura fun wa bayii ni pe ẹ o jere ohunkohun nipinlẹ Eko ri. Ti ẹ tun bomi sinu ibọn, tẹ ẹ n mu un pe ẹ o janfaani kankan nipinlẹ Eko ri.

Ẹ bọ sita kẹ ẹ wẹ ara yin mọ pe irọ lọrọ yii. Ẹ o le fi microphone (makirofoonu) ẹrọ amohundungbẹmu pa emi o, tẹ ẹ ba ni ẹ ni microphone, awa gan-an lẹnu lati sọrọ o.

“Iya kan lo bi yin, iya kan lo bi awa naa o. Ẹ ma ni ẹ ni microphone lati fi pa ẹnikẹni ti ko ba gbọrọ si yin lẹnu, pe microphone ni ẹ maa fi baye ẹ jẹ, pe tẹ ẹ ba sọ ọ titi ti wọn o ba gbọrọ si yin lẹnu, microphone ni ẹ fi n baye wọn jẹ.

Ati pe ti Gomina Sanwo-Olu ko ba gbọrọ si yin lẹnu, ẹ maa fi microphone baye ẹ jẹ ni. Ẹ o le fi microphone baye temi jẹ o. Ẹ fiṣẹ wa silẹ, ẹ fiṣẹ wa silẹ, Alaaji, ẹ jọọ, nitori Ọlọrun. Gbogbo agbara to wa lọwọ yin lonii, latara Aṣiwaju ati APC ni ẹ fi ni ohun ti ẹ n lo.

Ẹ fiṣẹ wa silẹ, National Union ipinlẹ Eko, ẹ fi silẹ, ẹ jọọ, ẹ jẹ ka rimu mi.

“Eeyan ṣiṣẹ fọdun mẹrin, inu yin dẹ dun, ẹ o kọrin bura yin pe ẹ o fẹẹ lọwọ ninu oṣi mọ. Ẹ o bara yin wi, eeyan n kowo wa na fun yin loju agbo, ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu Naira! Ẹ dẹ ṣi n tẹle iru ẹni bẹẹ pe ileri to ṣe ni ọjọ kọkanlelọgbọn, pe ko ma gbe agbara yẹn silẹ. Alaaji, ṣe o daa? Ṣe ẹ o lọmọ ni? Ẹlẹdaa wa maa jẹ yin niya, Ẹlẹdaa wa maa jẹ yin niya o.

“Nitori, irọ nla nla, tẹ ẹ ni ẹ o janfaani nipinlẹ Eko ri, inu ile itura Raddison Blu loke yẹn ni a ti ṣepade, ti ẹ ti n fibọn bura pẹlu o. Abi nijọba apapọ loke lọhun-un, ti ki i baa ṣe Aṣiwaju, ta lo mọ yin? Ẹ o le fi microphone pa emi o, nitori ẹ ti ni ẹni tẹ ẹ ba ti fẹẹ ba tiẹ jẹ lẹ maa n lo microphone fun. Gomina wa Sanwo-Olu, ẹ jọọ, ẹ o le paṣẹ ki olorin tun maa paṣẹ fun yin o. Ọlọrun a fun yin ṣe, ẹ ṣee sa”.

 

Bayii ni ọkunrin naa sọ ninu fidio ọhun pẹlu ẹdun ọkan.

Leave a Reply