Eyi ni bi awọn agbebọn ṣe ji awọn eeyan gbe n’Isinbọde-Ekiti

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Ọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii yoo jẹ manigbagbe fawọn eeyan ilu Isinbọde-Ekiti ati Ode-Ekiti, nijọba ibilẹ Ila-Oorun Ekiti, pẹlu bi awọn agbebọn kan ṣe da ibẹrubojo silẹ lagbegbe naa.

Awọn ẹruuku ọhun ti wọn jẹ mẹwaa niye la gbọ pe wọn deede kọ lu ibudo kan ti wọn ti n ta pako, eyi to wa loju ọna to so ilu mejeeji pọ, iṣẹ adigunjale ni wọn si kọkọ ṣe nigba ti wọn ko awọn oṣiṣẹ ibẹ ni papamọra.

Wọn gba owo atawọn nnkan ini mi-in ti wọn ba lọwọ awọn to ko sọwọ wọn ọhun, lẹyin eyi ni wọn ji ọkunrin kan ati obinrin kan gbe.

Bi wọn ṣe ko awọn eeyan naa ni wọn bọ si titi, ibẹ si ni ọkọ kan to gbe adari ileeṣẹ ijọba Ekiti kan ti ko si wọn lọwọ. Nigba ti wọn woye pe dẹrẹba ọkọ ọhun le fẹẹ sa lọ ni wọn da ibọn bo o, nigba to si fara pa lo duro.

Kia ni wọn gbe ẹni to wa ninu ọkọ atawọn meji to ku, wọn si wọ inu igbo lọ. Ṣugbọn ọkan ninu awọn meji ti wọn mu tẹlẹ sa mọ wọn lọwọ nigba to ya, eyi to fi ku awọn meji sọdọ wọn di asiko ta a pari akojọpọ iroyin yii.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun wa, ASP Sunday Abutu to jẹ alukoro ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe loootọ ni ẹni kan sa mọ wọn lọwọ, to si ku awọn meji.

O sọ ọ di mimọ pe ileewosan ni dẹrẹba ti wọn yinbọn lu wa to ti n gba itọju, ati pe awọn ọlọpaa ti n tọpasẹ awọn ajinigbe naa lati gba awọn to wa lọwọ wọn pada lai fara pa.

Titi di oni, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, awọn eeyan naa ko ti i bọ kuro ninu igbekun.

One thought on “Eyi ni bi awọn agbebọn ṣe ji awọn eeyan gbe n’Isinbọde-Ekiti

  1. Ejowo awon group amotekun ti egbe yoruba da sile nibo ni won wa ,see bi won o se mawo ni, ti Gbogbo kan yie baje tan , yoruba e je Ka ronu , o unbo o unbo leyin yoruba mawi soki loro

Leave a Reply