Eyi ni bi awọn Fulani afẹmiṣofo ṣe pa aadọta eeyan laarin ọjọ mẹrin

Adewumi Adegoke

Titi di ba a ṣe n sọ yii inu ibẹru-bojo ni awọn eeyan abule mẹsan-an kan ni agbegbe ijọba ibilẹ Kwande, nipinlẹ Benue, wa bayii, bẹẹ ni wọn ko si ti i le foju le oorun nitori apafọn tawọn Fulani darandaran pa eeyan bii aadọta kaakiri awọn abule to wa ni ijọba ibilẹ naa laarin ọjọ mẹrin sira wọn.

Alaga ijọba ibilẹ Tertswa Yarkbewan, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ keje, oṣu Kẹta yii, ṣalaye pe fun bii odidi ọjọ mẹrin lawọn Fulani afẹmiṣofo yii fi lọọ lugọ de awọn eeyan abule bii mẹsan yii, ninu eyi ti Adam, Iyarinwa, Waya Boagundu, wa, ti wọn si n pa wọn bii ẹran, bẹẹ ni ọpọ ninu awọn eeyan mi-in ti sa kuro ni awọn abule yii latari ikọlu awọn Fulani ọhun.

Alaga naa ni, ‘‘Ẹ wo bi wọn ṣe pa awọn eeyan mi bii ẹran, ohun ti a ti n gbọ tẹlẹ ni pe akọlu awọn Fulani waye, paapaa ju lọ ni Tuwan, ni agbegbe Kwande. Ṣugbọn nisinsinyii, gbogbo agbegbe ti ko ri akọlu awọn Fulani yii tẹlẹ ni wọn ti n ri i bayii. Ojoojumọ lẹ oo maa gbọ pe wọn ti pa eeyan mẹrin, wọn ti pa eeyan marun-un. Bi mo ṣe n ba yin sọrọ yii, a ko ti i le ṣọ pe iye eeyan bayii ni wọn pa, nitori oku ọpọ awọn eeyan naa ṣi wa ninu igbo ti wọn ko ti i ko wọn jade. Ṣugbọn ta a ba ni ka ka iye eeyan to ti ku latari ikọlu aarin ọjọ mẹrin yii, wọn ko le din ni aadọta.

Oludije sipo gomina ninu ẹgbẹ APC nipinlẹ naa, Hyacinth Alia, koro oju si akọlu yii gẹgẹ bo ṣe sọ ninu atẹjade kan ti Akọwe iroyin rẹ, Isaac Uzaan, gbe jade lorukọ rẹ. O fi aidunnu rẹ han si bi awọn Fulani darandaran naa ṣe n ya wọ abule ọhun, ti wọn si n pa awọn eeyan ni ipakupa. O ni o jẹ ohun to ba ni lọkan jẹ pe lasiko ti awọn ṣẹṣẹ dibo yan aarẹ tuntun, eyi ti i ṣe Aṣiwaju Bọla Tinubu, ti eto idibo ko si ti i pari ni wọn bẹrẹ akọlu ọhun.

Bakan naa ni Alaga ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ naa, Isaac Teryila, bu ẹnu atẹ lu iṣẹlẹ naa. O ni pipa awọn eeyan ni ipakupa yii le ṣakoba fun eto idibo gomina ti yoo waye ni ọjọ kọkanla, oṣu yii, nitori ibẹru ko ni i jẹ ki ọpọ jade lati dibo.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpa ipinlẹ naa, Aranbinrin Catherine Anene, sọ pe loootọ ni iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ, ṣugbọn awọn to ku ko to aadọta ti wọn pe e yii.

Leave a Reply