Adefunkẹ Adebiyi
Ajọ to n ri si iwa ajẹbanu ati kikowo ilu jẹ, Independent Corrupt Practices and other Related Offences Commission (ICPC), ti jẹ ko di mimọ pe ko din ni ọọdunrun ile ati ẹyọ kan (301 houses) tawọn ri gba lọwọ awọn oṣiṣẹ ijọba meji niluu Abuja.
Alaga ICPC, Ọjọgbọn Bọlaji Olufunmileyi Ọwasanoye, lo sọ eyi di mimọ lasiko ti wọn n ṣafihan awọn igbimọ to n ri si ọrọ ile gbigbe ati ilẹ, l’Ọjọbọ, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kẹwaa, ọdun 2021.
Bo tilẹ jẹ pe Ọwasanoye ko darukọ awọn oṣiṣẹ ọba meji ọhun, Alaga ICPC naa sọ ọ di mimọ pe awọn gba ile igba ati mọkanlelogoji (241) lọwọ ọkan ninu awọn oṣiṣẹ ọba ọhun, nibi to kọ wọn si kaakiri ilu Abuja. O ni ọgọta ile (60) lawọn gba lọwọ oṣiṣẹ ọba keji, nibi tiyẹn naa kọ wọn si lori ilẹ rẹpẹtẹ kan.
Lori bi iwa ole yii ṣe bọ si i fawọn oṣiṣẹ ọba meji ọhun, Ọwasanoye di ẹbi ẹ ru awọn ajọ to n ri si idagbasoke olu ilu Naijiria, iyẹn Federal Capital Development Authority (FCDA). O ni awọn ẹka naa ni wọn n lẹdi apo pọ pẹlu awọn oṣiṣẹ ọba ti iwa ajẹbanu yii fi ṣee ṣe.
Alaga ICPC naa tẹsiwaju pe nigba ti ko si akọsilẹ to kunna latọdọ awọn FCDA, to jẹ niṣe ni awọn oṣiṣẹ ijọba n fi ọgbọn awuruju gba ilẹ lọwọ wọn, ti ko si si iwe to n ti ilẹ ti wọn gba lẹyin, to jẹ ko si pe wọn forukọ ẹni to gba ilẹ sibi to yẹ ko wa, ti kaluku n ṣe bo ṣe fẹ, to si n mu ohun to ba wu u ninu ilẹ ijọba, iyẹn lo fa a ti wọn fi ri ole nla naa ja.
“ Bi ẹ ba rin kaakiri Abuja yii bayii, ẹ maa ri ọpọlọpọ ile ẹsteeti ti wọn kọ kalẹ, agaga laarin igboro, ṣugbọn ko seeyan nibẹ, ko sẹnikan to n gbe ninu wọn. To ba jẹ pe awọn to kọ ọ yawo kọ ọ loju ọja ni, wọn ko ni i fi i silẹ bẹẹ ko ma si eeyan nibẹ. Eyi jẹ ko ye wa pe owo ilu ti wọn feru ko ni wọn fi kọ awọn ile ọhun”