Francis Iyiade
Awọn meji to ku ninu awọn ọmọ marun-un ti ọkọ iya wọn, iyẹn Ojo Joseph dana sun mọle loru ọjọ Ẹti, Furaide mọju ọjọ Abamẹta, Satide ọsẹ to kọja yii naa ti royin ohun toju wọn ri f’ALAROYE lasiko ta a ṣabẹwo sibi ti wọn ti n gba itọju lọwọ ni ọsibitu ijọba apapọ to wa niluu Ọwọ.
Ọkan ninu awọn ọmọ ọhun to p’orukọ ara rẹ ni Bisọla Akinfọlarin to kọkọ ba wa sọrọ ni lati oju oorun loun ti ṣakiyesi pe ẹnikan n da nnkan tutu soun lara.
O ni gbogbo ero ọkan oun ni pe o ṣee ṣe ko jẹ omi ti ẹnikan n gbe kọja laarin ọdẹdẹ ti awọn sun si lo ṣee si da si oun lara nitori ki i ṣe igba akọkọ niyẹn ti iru iṣẹlẹ bẹẹ maa n waye si awọn ninu okunkun ti awọn maa n sun si.
Ọmọbinrin to jẹ akọbi ninu awọn ọmọ mararun-un ọhun ni bi oun ṣe n gbiyanju ati dide lati fidi ohun to n ṣẹlẹ mulẹ ni oun ri i ti ẹnikan ṣana si awọn lara, eyi lo mu ki oun maa kigbe ina, ina, ki awọn eeyan le waa ran awọn lọwọ.
Bisọla ni ohun oun ti wọn n gbọ l’awọn araadugbo kan fi jade loru ọganjọ ọhun, ti wọn si gbiyanju ati ba awọn pana to n jo lara awọn, ti wọn si gbe awọn aburo oun mẹta jade laimọ pe o si ku abikẹyin mama awọn ti orúkọ rẹ n jẹ Tayọ, ẹni ọdun meje sinu ina.
O ni gbogbo ipa ti mama awọn sa lati ri ọmọbìnrin naa gbe lo ja si pabo latari ina to ti fẹju ti ko si ṣee sare wọ mọ, ori akitiyan yii lo ni iya awọn ti fẹsẹ mejeeji jona.
Ọmọbinrin to ti to bii ọmọ ọdun mejidinlogun ọhun ni awọn araadugbo ni wọn gbe ọkọ gọọfu kan silẹ eyi ti wọn fi ko gbogbo awọn lọ si ile-iwosan ẹkọsẹ iṣegun to wa niluu Ondo nibi ti wọn ti ṣeto ambulansi to pada gbe awọn wa si ọsibitu ijọba apapọ to wa l’Ọwọ.
Ohun ta a gbọ ni pe alaga ijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ondo, Ọnarebu Akinsulirẹ Ayọdeji Ebenezer lo ra epo sinu ọkọ ambulansi ti wọn fi gbe awọn mẹrin to ku lọ siluu Ọwọ ni nnkan bii aago mẹfa idaji ọjọ Abamẹta, Satide ọsẹ to kọja lọ naa.
O ni inu mọto ni ọkan ninu awọn mẹrin yooku ku si loju ọna, lasiko ti wọn n ko awọn bọ, bẹẹ ni Tọpẹ, ti i ṣe ẹnikẹta awọn, ku si ile-iwosan naa laaarọ ọjọ Isẹgun, Tusidee.
O ni loootọ ni ede aiyede kan waye laaarin iya awọn ati ọkọ rẹ lalẹ ọjọ Ẹti, Furaide, ṣugbọn oun ko le sọ pato ohun to dija silẹ laarin wọn. O ni ori airyanjiyan naa loun atawọn aburo oun fi wọn si ti awọn fi lọọ sun nitori ikilọ ti àwọn ti gba tẹlẹ pe awọn ko gbọdọ maa da sọrọ awọn mejeeji ti wọn ba ti n ja.
Bisọla ni Ojo to jẹ ọkọ iya awọn loun kọkọ ri ni kete ti oun fo dide lati ori ibusun ti awọn sun si latari ina to n jo awọn.
Aburo rẹ, Tobi Akinfọlarin ni ki ọrọ ina ọhun too bẹrẹ rara loun ti kọkọ ri Ojo Joseph to n rin kaakiri ibi ti awọn sun si laarin oru.
Ọmọkunrin ẹni ọdun mejila ọhun ni ooru to mu lọjọ naa ni ko jẹ ki oun sun àsùnwọra, iyẹn lo si jẹ ki gbogbo iṣẹlẹ naa ṣoju oun gbangba.
O ni ibi tí oun ti n fi beba kan fẹ atẹgun sara oun loun ti ṣàkíyèsí pe wọn n da nnkan kan si awọn lara nibi ti awọn sun si, Tobi ni itọ loun pe e tẹlẹ, amọ ọrọ naa pada ye oun daadaa lẹyin-ó-rẹyìn pé bẹntiroolu ni, nigba ti oun ri ọkọ iya awọn to ṣana si awọn lara ti ina si bẹrẹ sii jo.
Ninu ọrọ Abilekọ Esther Ojo to jẹ iya awọn ọmọ ọhun, o ni ọdun karun-un ree toun ati Ojo ti fẹ ara wọn ti Ọlọrun si fi ọmọ meji, Taye ati Kẹhinde ta awọn lọrẹ.
O ni Ojo fun oun ni ẹgbẹta Naira ko too jade lọ lọjọ Iṣẹlẹ naa lati fi wa ounjẹ, lara owo naa lo ni oun ti ra ogi ti oun fẹẹ fi ro ẹkọ f’awọn ibeji to n gbe lọwọ ti oun si tun fi eyi to ku ra àgbo.
Ija lo ni ọkùnrin to n ṣiṣẹ lagilagi ọhun gbe ko oun loju nigba to pada wọle lori ẹsun to ni o fi kan oun pe ṣe loun ko awon ibeji naa tọrọ baara lọ. Bakan naa lo ni o tun ba oun ja latari aiba lara ounjẹ to fowo rẹ silẹ nile.
Ni nnkan bii aago marun-un irọlẹ lo ni o jade lọọ ra epo bẹntiroolu eyi to ni oun fẹẹ lọọ fi ṣiṣẹ lagilagi to n ṣe ninu oko lọjọ keji.
Iya ibeji ni oun to kọkọ fu oun lara ni bí Ọjọ ko ṣe tete sun lalẹ ọjọ naa, o ni ṣe lo ń rin kiri ile ti oun si n beere lọwọ rẹ boya o ni oun to n ṣe e ti ko fi sún ṣugbọn to dahun pe ko si ohunkóhun.
Eyi to kere ju ninu awọn ọmọ marun-un akọkọ ti oun bi lo kọkọ waa ji oun loju oorun gẹgẹ bii iṣe rẹ pe oun fẹẹ tọ ti oun si dide lati lọọ gbe e tọ.
Abilekọ Esther ni ori ibùsùn oun loun tun pada si lẹyin ti ọmọ naa tọ tan, bí oorun ṣe fẹẹ maa mú un lọ ni nnkan bii aago mẹta aabọ oru lo ni oun gbọ igbe Bisọla to jẹ akọbi oun to n pariwo ina.
O ni Ọjọ ti maa n sọ foun tẹlẹ pe koun ko awọn ọmọ naa pada lọọ fun baba wọn, iṣẹ ti baba wọn n ṣe lóko lo ni ko jẹ káwọn ọmọ rẹ maa gbe lọdọ rẹ, gbogbo ọjọ Abamẹta, Satide ọsọọsẹ nikan lo ni wọn maa n lọ sọdọ rẹ to ba ti de lati oko.
Abilekọ ẹni ọdun marundinlogoji naa ni ko ohun ko tii ri eyikeyii ninu awọn ẹbi Ojo ki wọn yọju tabi waa ki awọn ni ọsibitu lati ọjọ to ti pa itu ọwọ rẹ, o ni àwọn mọlẹbi oun nikan loun n ri ti wọn n nawo nara le oun lori.
O ni ọpẹlọpẹ awọn ọlọpaa ti awọn ara àdúgbò pe ni wọn ra Ojo mu nigba to ko awọn ibeji tìrẹ gba ọna ẹyinkule tó fẹẹ maa salọ lẹyin to dana sun awọn ọmọ ọlọmọ tan.
Obinrin naa waa rawọ ẹbẹ si ijọba atawọn araalu lati dide iranlọwọ fun itọju oun atawọn ọmọ yooku, (ko tii gbọ nipa iku ọmọ rẹ kẹta to n jẹ Tọpẹ lasiko ta a lọọ fọrọ wa a lẹnu wo).
Ọjọruu, Wẹsidee ọsẹ to kọja ni Ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ṣe afihan Ojo f’awọn oniroyin ki wọn le fọrọ wa a lẹnu wo lori ohun to ri to fi huwa ọdaju to hu.
Ọkunrin to pe ara rẹ lẹni ọdun mẹrinlelọgọta ọhun ni inu osu kejila ọdun ta a wa yii ni yoo ṣẹṣẹ pe ọdun meji ti oun ati Esther ti fẹ ara awọn.
O ni ọmọ meji pere lo jẹwọ foun pe oun ti bi tẹlẹ, igba to ko ọmọ de lo ni oun ṣẹṣẹ mọ pe wọn to marun-un.
Ojo ni o pẹ toun ti n ba obinrin naa ja pe ko ko awọn ọmọ naa lọ fun baba wọn ti ko gbọ, ọrọ ọhun lo ni awọn ti fa titi de ọdọ awọn ajafẹtọọ ṣugbọn ti ko loju.
O ni oun mọ-ọn mọ dana sun wọn latari bi wọn ṣe maa n wa lẹyin iya wọn nigbakuugba ti awọn ba jọ n ja, bakan naa lo ni obinrin naa tun maa n febi pa oun nitori awọn ọmọ rẹ.
Alukoro Ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Funmilayọ Ọdunlami ti ni Ojo ko nii pẹẹ foju b’ale-ẹjọ ni kété ti iwadii ba ti pari lori ọrọ rẹ.