Jọkẹ Amọri
Bianca Ojukwu, iyawo ọkan ninu awọn agba oṣelu ilẹ Ibo to ti doloogbe bayii, Odumegwu Ojukwu, ti ṣalaye idi to fi gba iyawo gomina ipinlẹ Anambra tẹlẹ, Ebele Obiano, leti lasiko ti gomina tuntun nipinlẹ naa, Ọjọgbọn Charles Soludo, n gbọpa aṣẹ.
Nigba ti obinrin naa n ṣalaye fun ileesẹ tẹlifiṣan Arise, ninu ifọrọwerọ ti wọn ṣe fun un lo ti ṣalaye pe, ‘‘Ni ọjọ Ẹti, Furaidee, ti eto naa waye, iyawo gomina yii ko si nibi eto yii nigba ti wọn bẹrẹ, lẹyin-o-rẹyin lo too de, iyẹn lẹyin bii wakati kan ti eto naa ti bẹrẹ.
‘‘Mi o tiẹ ṣe bii ẹni pe mo ri i nigba to de. Si iyalẹnu mi, afi bo ṣe n bọ taara lọdọ mi, mo ro pe o n bọ waa ki mi ni. Afi bo ṣe bẹrẹ si i pariwo le mi lori fatafata, to si n bu mi, to si n fi mi ṣe yẹyẹ, to n sọ pe kin ni mo waa ṣe nibi, awọn ọrọ ti ko bojumu lo n sọ jade lẹnu si mi. O ni ṣe mo wa fun ayẹyẹ ọjọ to gbẹyin tawọn maa lo lọọfiisi ni.’’
‘‘Mi o tiẹ da a lohun, ṣugbọn niṣe lo bẹrẹ si i fọwọ ti mi lejika, to tun n pariwo.
‘‘Pẹlu bi mi o ṣe da a lohun bo ṣe n bu mi to, nitori awọn eeyan to wa nitosi ti ni ki n ma da a lohun, ẹẹmeji ọtọọtọ ni mo sọ fun un pe ko yee fọwọ gun mi lejika. Ṣugbọn ko dahun, o tun n fọwọ gun mi lejika, bẹẹ lo fọwọ gun mi lori to fẹẹ ṣi gele ti mo we.
‘‘Asiko yẹn ni mo dide lati gbeja ara mi lọwọ ẹ, ti mo si fun un ni igbaju olooyi ko too loun maa kọ lu mi. Mo yọ wiigi to de sori. Asiko yẹn lo fọwọ rẹ mejeeji wa wiigi naa mọri, to si n gbiyanju lati gba wiigi naa lọwọ mi.
Obinrin naa ni iyalẹnu lo jẹ foun nigba ti oun gbọ oorun ọti lile to n jade lẹnu iyawo gomina yii nigba ti awọn eeyan to wa nitosi n gbiyanju lati la awọn.
‘‘Bawo ni iyawo gomina yoo ṣe mu ọti yo to bẹẹ niru asiko yẹn. Mo duro titi ti eto naa fi pari, mo si kuro nibẹ lai ba ọmọluabi mi jẹ.’’
Bianca lo pari ọrọ rẹ bẹẹ.