Eyi nidi ti Alaafin ati Olubadan ko ṣe le wọle sibi ayẹyẹ papa-iṣere Lekan Salami-Makinde

Faith Adebọla

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde ti fesi lori ọrọ abuku kan to n ja ranyin lasiko yii pe awọn agbofinro wọ ori ade nilẹ, wọn gbegi dina fun Alaafin Ọyọ, Ọba Lamidi Adeyẹmi, kẹta ati Olubadan tilẹ Ibadan, Ọba Saliu Adetunji, wọn o jẹ kawọn ọba naa raaye wọle sibi ayẹyẹ ṣiṣi papa-iṣere Lekan Salami (stadium) to waye l’Ọjọruu, Wẹsidee, to kọja yii.

Gomina Makinde ni irọ ni o, awọn agbofinro ko tabuku sori ade, niṣe ni wọn gba awọn dẹrẹba wọn lamọran lati lọọ gba geeti keji wọle sibi ayẹyẹ naa latari bi obitibiti ero ṣe ya bo geeti ki-in-ni, ti lilọ bibọ ọkọ si di wahala nla lọjọ naa.

Ṣaaju lawọn agbẹnusọ awọn ọba ọhun, Ọgbẹni Bọde Durojaye, agbẹnusọ fun Alaafin, ati Oloye Adeọla Ọlọkọ, agbenusọ fun Olubadan, ti sọ fawọn oniroyin pe niṣe lawọn ẹṣọ alaabo abẹbẹlukege yari mọ awọn dẹrẹba ati ikọ to tẹle awọn ọba alaye naa lọwọ, wọn taku, wọn o jẹ ki wọn wọle, titi tawọn ọba naa fi binu pada sile, ti wọn ko si le debi ayẹyẹ ti wọn tori ẹ jade ọhun.

Durojaye sọ fawọn oniroyin lọjọ Tọsidee naa pe awọn onigbonara ẹṣọ alaabo ti wọn fẹẹ jiṣẹ ju ibi toniṣẹ ran wọn lọ lawọn pade lẹnu ọna, nigba ti awọn si parọwa fun wọn, wọn ni awọn le gba kawọn kabiyesi wọle, ṣugbọn awọn o ni i jẹ kawọn ẹṣọ alaabo atawọn ikọ to ba ọba rin wọle, eyi lo mu kawọn ṣẹri pada latẹnu geeti naa.

Ọrọ yii lo mu kawọn eeyan bẹrẹ si i bẹnu atẹ lu Gomina Makinde atawọn agbofinro pe iwa abuku gbaa ni wọn hu, awọn ọba ilẹ wa ki i ṣẹni arifin, wọn ni ko yẹ kọrọ naa ri bẹẹ rara.

Ṣugbọn ninu alaye ti Akọwe iroyin fun Gomina Ọyọ ṣe ninu atẹjade kan to fi lede lọjọ keji iṣẹlẹ yii lorukọ Ṣeyi Makinde, o ni aigbọra-ẹni-ye lo waye laarin awọn dẹrẹba to gbe awọn ori-ade naa pẹlu awọn agbofinro.

Bo ṣe wi, niṣe lawọn agbofinro naa ni ki wọn gbe awọn ọba alaye naa gba geeti keji, yatọ si pe ero ko fi bẹẹ si ni geeti yii bii ti akọkọ, ti yoo si ṣee ṣe fun wọn lati tete wọle, ibi ti wọn yoo wọle si sun mọ aaye ijokoo ọlọlaa (VVIP zone) ti wọn ti pese aga awọn ori-ade naa si, wọn ko si ni i ṣẹṣẹ maa gun akasọ ki wọn too debẹ, bii ti geeti ki-in-ni.

O ni eyi yoo tubọ rọrun fawọn ọba alade naa, paapaa nitori ipo agba ati ọjọ-ori wọn, awọn fẹẹ da agba laamu ni wọn ṣe gba wọn lamọran naa.

O ni ọrọ katikati niroyin tawọn kan n gbe pooyi atẹ ayelujara pe Makinde fẹẹ fi awọn ọba naa wọlẹ ni, awọn si ti wa lojufo lati mu ẹnikẹni ti iwadii ba fihan pe o ṣagbatẹru iroyin ibajẹ bẹẹ.

“Gomina Ṣeyi Makinde fẹ lati sọ kedere pe awọn n reti Alaafin ati Olubadan nibi ayẹyẹ ọjọ naa, tori ẹ ni wọn ṣe pese ijokoo ọlọla, ti wọn ti ṣami orukọ awọn ọba alaye naa si i.”

Leave a Reply