Eyi nidi ti igbeyawo Funkẹ Akindele fi daru patapata

Aṣiri tu!
Eyi nidi ti igbeyawo Funkẹ Akindele fi daru patapata
Faith Adebọla

Bii iso buruku ni atẹgun ọrọ naa fẹ wọle yẹẹ, ọpọ eeyan lo si n ṣe ni kayeefi titi di ba a ṣe n sọ yii, nigba ti wọn gbọ pe igbeyawo gbajugbaja oṣere tiata ilẹ wa nni, Funkẹ Akindele-Bello, tawọn eeyan mọ si Jẹnifa, ti tuka patapata.
Bo tilẹ jẹ pe ṣaaju asiko yii ni awuyewuye ti n lọ lori ẹrọ ayelujara nipa ajọṣe ti ko dan mọran laarin Funkẹ Akindele ati ọkọ rẹ, Abdulrasheed Bello, ti inagijẹ rẹ n jẹ JJC Skillz, onkọrin taka-sufee igbalode, to tun maa n ba awọn olorin gbe awo jade, sibẹ, ohun to ya awọn eeyan lẹnu, to si mu ki wọn gbagbọ pe ẹkọ ko ṣoju mimu laarin ololufẹ mejeeji ọhun mọ ni pa ọkọ Funkẹ funra ẹ lo kede faye lọtẹ yii pe igbeyawo awọn ti fori ṣanpọn.
Ṣe ẹnu onikan la ti i gbọ ‘pọun-un,’ JJC Skillz funra ẹ lo kọ ọ sori Instagiraamu rẹ l’ọgbọnjọ, oṣu Kẹfa yii, pe:
“Ẹyin ọrẹ ati mọlẹbi, Mo fẹ kẹ ẹ mọ pe emi ati Funkẹ ti pinya o. Nigba ti a fi jọ wa papọ, a jọ gbadun ọpọ nnkan papọ, a si bimọ meji to rẹwa daadaa. Ṣugbọn lati ọdun meji sasiko yii ni nnkan ko ti rọgbọ laarin wa, ko tiẹ rọgbọ rara ni. Mo mọ pe mo ti gbiyanju gbogbo agbara mi lati wa ojuutu si ọrọ yii, ṣugbọn nibi tọrọ naa de bayii, o ti kọja atunṣe.
“Funkẹ ta ku pe mo gbọdọ ko jade nile foun, mo si ti ko jade lati oṣu mẹta sẹyin, ko si ti i ṣee ṣe fun emi ati ẹ lati jọ jokoo, lati jiroro nitunbi inubi, nipa ọjọ iwaju igbeyawo wa, yatọ si pe a jọ wa si ayẹyẹ awọọdu AMVCA kan laipẹ yii. Idi ti mo fi n ṣe ikede yii ni pe mo fẹ ki gbogbo eeyan mọ pe emi ati ẹ ti pin gaari, kaluku ti wa lọtọọtọ. Loootọ, a ṣi lawọn ọrọ pataki lati jokoo sọ, bii ọrọ nipa abojuto awọn ọmọ ati ọdọ ẹni ti wọn maa wa, tori iyẹn ṣe koko, titi kan ọrọ nipa okoowo to da wa pọ, ti a ni lati yọpa yọsẹ wa, ṣugbọn mi o ṣiyemeji pe a maa yanju awọn yẹn bo ba ṣe gba, to ba ya.”
Bayii ni ọkọ Funkẹ Akindele ṣiṣọ loju eegun iṣẹlẹ ọhun.
Tẹ o ba gbagbe, oriṣiiriṣii awuyewuye ati fa-a-ka-ja-a to ti n lọ laarin tọkọ-taya naa ko ṣẹyin awọn ẹsun ọlọkan-o-jọkan ti wọn fi n kan ara wọn, ati bo ṣe jẹ pe bi awo ṣe n lu lawo n jo lori ẹrọ ayelujara, nipa awọn mejeeji.
Asiko kan ni wọn fẹsun kan Funkẹ Akindele pe ko ṣe daadaa si ọmọ ọkọ rẹ to ba nile, iyẹn ọmọkunrin ti JJC Skillz ti bi tẹlẹ. Bi ina ọrọ naa ṣe n ru lo mu ki iya ọmọkunrin naa, iyẹn iyawo Bello tẹlẹ, da si i, o ni ki Abdulrasheed kilọ funyawo ẹ, Funkẹ, tori gbogbo bo ṣe n ṣe si ọmọ oun, to n sọrọ kobakungbe, loun n gbọ. Ṣugbọn kaka ki ewe agbọn ija naa dẹ, niṣe lo n le si i, eyi lo si fa a ti obinrin naa fi gbe fọto Funkẹ Akindele ati ọkọ ẹ pẹlu awọn ibeji wọn sita, o fi oju wọn han kedere ninu fọto ọhun, o ni gbogbo ohun ti Funkẹ n bo loun yoo ṣiṣọ loju ẹ. Ṣe ṣaaju asiko yii, Funkẹ ati ọkọ rẹ ko foju awọn ibeji rẹ naa han sode, gbogbo fọto loriṣiiriṣii ti wọn n ya, ti wọn n gbe sori ẹrọ ayelujara wọn, akọyinsi awọn taye-kẹyin naa ni wọn n gbe sibẹ. O daju pe ohun ti obinrin yii ṣe dun Funkẹ Akindele gan-an.
Lẹyin eyi ni ọmọ ọkọ Funkẹ tun taṣiiri tọkọ-taya naa sori ayelujara, o ni igbe aye ekute ati ologbo ni baba oun ati iyawo ẹ n gbe, awọn mejeeji ko ri ara wọn soju mọ, wọn kan n dibọn loju aye ni, ẹrin o denu ni wọn n ṣe fun ara wọn. Ọmọkunrin naa tun sọ pe wọn o gbe papọ mọ.
Ṣaaju asiko yii ni awuyewuye mi-in ti n ja ranyin pe ọkọ Funkẹ Akindele yii n fọbẹ ẹyin jẹ iyawo rẹ niṣu, wọn lo n yan ale nita, eyi lo si bi Funkẹ ninu, bo tilẹ jẹ pe ko sẹni to fidi ẹsun naa mulẹ. Bẹẹ lọmọ yii ni Funkẹ paapaa n yan ale nita.
Nibi tọrọ de bayii, ko sẹni to le sọ pato boya ija ajatuka ni tagbaarin ni ija yii yoo jẹ, abi yoo jẹ ija ahọn ati eyin, ti yoo tun pari nigba ti ounjẹ mi-in ba de.
Ọdun 2016 ni Funkẹ ati Bello fẹra, ilu London, lorileede United Kingdom, ni wọn ti lọọ ṣayẹyẹ igbeyawo wọn, Ọlọrun si fi ibeji ta wọn lọrẹ lẹyin oṣu diẹ. Igbeyawo naa waye lẹyin ọdun mẹjọ ti igbeyawo akọkọ ti Funkẹ Akindele ati ọkunrin oloṣelu kan, Kẹhinde Oloyede, ṣe, fori ṣanpọn, bo tilẹ jẹ pe ko si ọmọ laarin wọn. Lẹyin eyi ni Oloyede di alaga ijọba ibilẹ Oṣodi Isọlọ, l’Ekoo, ipo naa lo si wa di ba a ṣe n sọ yii.

Leave a Reply