Ẹyin Fulani, ẹ yee gbe ninu igbo, ẹ maa bọ nigboro-Oluwoo

Florence Babaṣọla

 

Oluwoo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi, ti fẹsun kan awọn aṣaaju ilẹ Yoruka kan pe awọn ni wọn wa nidii ilu ogun to n dun lemọlemọ lorileede yii bayii.

Ninu atẹjade kan to fi sita lọ̣̣̣jọ Aiku, Sannde lo ti sọ pe ṣe lawọn eeyan naa n ṣe bẹẹ fun iwa imọtara-ẹni nikan ati nitori ohun ti wọn fẹẹ da ninu oṣelu.

O ni ọrọ wahala eto aabo ti orileede yii, paapaa, lapa Guusu Iwọ-Oorun, n koju bayii ko ṣẹyin ọrọ idibo ipo aarẹ ti ọdun 2023.

Ọba Akanbi ṣalaye pe “A mọ awọn aṣaaju Yoruba yi wọn n lulu ọtẹ bayii, nitori oṣelu si ni. Gbogbo rẹ ko ṣẹyin bi wọn ṣe n ro pe ẹnikan fẹẹ dupo aarẹ, ti wọn ko si fẹ ki ẹni naa debẹ.

“Wọn mọ pe ilẹ Yoruba ni aarẹ yoo ti wa lọdun 2023, wọn ko si fẹ ko ṣe e ṣe, ẹni ti wọn si n tori rẹ da wahala silẹ gan-an ko ti i sọ pe oun fẹẹ di aarẹ, ki lo wa fa ikorira gan an?

“Emi o ni i laju silẹ ki ẹnikẹni dana ogun lorileede yii, gbogbo awọn ti wọn si n pete ogun nilẹ Yoruba, paapaa, niluu Eko, ko ni i ni ẹyin rere”

Oluwoo ke si awọn agbofinro lati dọdẹ ẹnikẹni to ba n huwa janduku lorileede yii; yala ọmọ Yoruba tabi Fulani, ki wọn si gbe wọn lọ sile-ẹjọ lona to tọ.

Bakan naa lo rọ awọn Fulani lati ran ijọba lọwọ lati ṣawari awọn ti wọn ba jẹ ọdaran laaarin wọn. O ni ki wọn yee gbe ninu igbo, ki wọn maa bọ laaarin ilu.

O tun ke sijọba lati gbe eto ilanilọyẹ kalẹ fawọn Fulani lori ọna igbalode ti wọn le gba maa sin maaluu wọn, ko ma baa si wahala mọ pẹlu awọn agbẹ ilẹ Yoruba.

 

Leave a Reply