Kọlawọle n lọ ṣẹwọn gbere l’Akurẹ, awọn ọmọleewe keekeeke mẹrin lo fipa ba lo pọ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

 

 

 

Adajọ Ile-ẹjọ giga kan l’Akurẹ ti dajọ ẹwọn gbere fun baba agbalagba kan, Kọlawọle Apoti, lẹyin to jẹbi ẹsun fifipa ba awọn ọmọ keekeekee mẹrin lo pọ.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, awọn ọmọdebinrin ta a forukọ bo laṣiiri ọhun ni wọn jẹ akẹkọọ ileewe St Michael, to wa l’Akurẹ. Eyi to dagba ju ninu wọn lo jẹ ọmọ ọdun mẹrinla, nigba tawọn mẹta yooku ko ti i ju bii ọmọ ọdun mejila lọ, ọdun kẹta si ree ti wọn lo ti n ba wọn lo pọ ki asiri rẹ too pada tu.

Ori eyi to jẹ ọmọ ọdun mẹrinla lo kọkọ ti bẹrẹ, nigba to ya lo n bẹ ọmọbinrin naa lọwẹ lati maa tan awọn ọrẹ rẹ wa ba a nile, nibi to ti n fipa ba wọn lo pọ, to si n fun ọkọọkan wọn lọgọrun-un naira pere lẹyin to ba ṣe e tan.

Ko sẹni to laya lati sọ ohunkohun fawọn obi rẹ ninu wọn, ṣe ni wọn n fi kinni ọhun ṣe osun, ti wọn fi n para latari iku to fi n dẹru ba wọn.

Ẹnikan to ba awọn mẹrẹẹrin nibi ti wọn ti ja lori ẹgbẹrun kan naira ti Kọlawọle fun wọn lo fipa wọ gbogbo wọn lọ sọdọ igbakeji olukọ agba ileewe wọn lọjọ kẹrin, osu kẹfa, ọdun 2019.

Ọjọ naa ni wọn ti fiṣẹlẹ yii to awọn ọlọpaa leti lẹyin ti wọn jẹwọ gbogbo itu ti baba ẹni ọdun mọkanlelaaadọta ọhun ti fi wọn pa.

Ileesẹ to n ri sọrọ obinrin nipinlẹ Ondo lo ṣeto bi wọn ṣe ko awọn ọmọdebinrin naa lọ sileewosan fun ayẹwo lati mọ boya loootọ ni wọn ti mọ ọkunrin.

Awọn esi ayẹwo ọhun pẹlu akọsilẹ wọn ni tesan ni wọn ko jọ ti wọn fi pe ọdaran naa lẹjọ sile-ẹjọ giga to wa l’Akurẹ.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ lọsẹ to kọja, Onidaajọ Oluwatoyin Akeredolu ni gbogbo ẹri tawọn olupẹjọ fi siwaju ile-ẹjọ naa lo fidi rẹ mulẹ pe loootọ ni olujẹjọ jẹbi ẹsun ifipabanilopọ ti wọn fi kan an.

Adajọ ran an ṣẹwọn gbere gẹgẹ bii ijiya fun jijẹbi ẹsun naa.

 

Leave a Reply