Lati ri i pe awọn ọmọ wa, awọn ọdọ ati agbalagba laarin wa ri ohun mu ṣọgbọn ni a ṣe ka itan Igbesi-aye Oloye Obafẹmi Awolọwọ sinu fidio, ki o le je ẹkọ fun ọmọ Yoruba gbogbo. Ọdun 2019 ni a ti tẹ iwe yii jade pẹlu aṣẹ lati ọdọ Obafẹmi Awolọwọ Foundation, labẹ akoso Ambassador Tokunbo Awolọwo-Dosumu. Budo Agbaye to n ri si Iṣẹ-Ọna ati aṣa Yoruba (Internationa Centre For Yoruba Arts and Culture) ni Yunifasiti Ibadan lo ni ka ka iwe naa si etigbọọ yin. O ya, ẹ jẹ ka jọ gbadun ẹ.