FRSC kilọ fawọn awakọ nitori abala ti wọn ṣi ni Lotto si Deeper Life

 Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Nitori ki sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ ma baa pọ ju lasiko ọdun Keresimesi loju ọna marose Eko s’Ibadan ni wọn ṣe ṣi abala kan Lotto si Deeper Life, loju ọna naa bayii, eyi si ti mu ki ajọ FRSC to n ri si aabo loju popo kilọ fawọn awakọ, pe ki wọn ma tori pe wọn ṣi ọna naa maa sare buruku.

Ọjọ Abamẹta, Satide, to kọja yii, ni ọga agba FRSC nipinlẹ Ogun, Kọmandanti Ahmed Umar, kilọ yii l’Ọta, nipinlẹ Ogun.

O ṣalaye pe ipinnu ati ṣi ọna yii ki i ṣe fun nnkan mi-in, bi ko ṣe lati din sunkẹrẹ-fakẹrẹ ku loju ọna yii lasiko ọdun.

Umar tẹsiwaju pe iṣẹ o ti i pari loju ọna yii, wọn kan ṣi ibi ti wọn ṣi yii fun ọdun ni. O ni ti ọdun ba ti pari, iṣẹ oju ọna yii yoo bẹrẹ pada.

 

Fun idi eyi ni ajọ alaabo yii ṣe ni kawọn awakọ jinna si ere asapajude, gbigba ọna ọlọna, lilo foonu  lasiko ti wọn n wa ọkọ atawọn iwa mi-in to lodi sofin irinna, wọn ko si gbọdọ sare kọja ẹẹdẹgbẹta kilomita ni wakati kan (50km per hour).

Ṣe lọjọ Ẹti to kọja ti i ṣe ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kejila, eeyan mẹta ni ajọ yii fidi ẹ mulẹ pe wọn dagbere faye ni Interchange, loju ọna yii kan naa.

Eyi waye nigba ti ọkọ Lexus kan ti ko ni nọmba, lọọ rọ lu mọto Toyota Tundra ti nọmba ẹ jẹ AGL 254HB,  to si pa ọkunrin meji ati ọlọmọge kan to duro jẹẹjẹ lẹbaa ọna yii ti wọn n wa mọto ti yoo gbe wọn lọ sibi ti wọn n lọ.

Ẹsẹkẹsẹ ni ọlọmọge naa ku gẹgẹ bi wọn ṣe wi, awọn ọkunrin meji si ku pẹlu, bẹẹ ni ọkunrin kan ṣeṣe ni tiẹ.

Ko sohun to fa ijamba ọwọ aago meje kọja iṣẹju meji aarọ naa ju ere buruku lọ gẹgẹ bi Umar ṣe wi.

O ni awakọ to wa Lexus naa n yi ori ọkọ rẹ pada, bẹẹ lo tun n sare, nibi to ti rọ lu mọto mi-in atẹni to duro rẹ jẹẹjẹ niyẹn.

Ile igbokuu-si to wa ninu  ọsibitu Idẹra, ni Ṣagamu, ni wọn ko awọn oku mẹtẹẹta lọ, ẹni to fara pa nikan ni wọn gbe lọ si wọọdu to ti n gbatọju.

Lati dẹkun awọn iṣẹlẹ to n fa iku ojiji bii eyi ni FRSC ṣe tun n kilọ, paapaa b’ọdun ṣe n lọ sopin lasiko yii.

Leave a Reply