Fulani darandaran tun ya wọ ilu Okelusẹ, wọn paayan meji, wọn tun ṣe awọn mi-in leṣe

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Eeyan meji lo ku, nigba tawọn mi-in tun fara gbọta ìbọn ninu akọlu tawọn Fulani darandaran kan ṣe siluu Okelusẹ nijọba ibilẹ Ọsẹ lalẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ ta a wa yii.

Awọn janduku agbebọn ọhun la gbọ pe wọn sina ibọn bolẹ lasiko ti wọn ya wọ ilu ọhun ni nnkan bii aago mẹsan-an alẹ, ninu eyi ti wọn ti yinbọn pa manija ileepo kan ti wọn porukọ rẹ ni Abọrọwa Ọladimeji.

Oloogbe ọhun, ẹni tawọn eeyan mọ si Popular, ni wọn lo pade iku ojiji nigba to n mura lati maa lọ sile lẹyin iṣẹ ọjọ naa.

Aarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, lariwo tun ta pe ọkan ninu awọn to fara gbọta ninu iṣẹlẹ naa tun ti dagbere faye nileewosan to ti n gba itọju.

ALAROYE fidi rẹ mulẹ pe awọn eeyan ilu ọhun wa ninu ibẹru lọwọlọwọ, ti ko si sẹni to tii laya lati lọ sibikibi latari akọlu tuntun to ṣẹṣẹ waye naa.

Eyi ni yoo jẹ igba kẹta tawọn Fulani darandaran n ṣe akọlu sawọn eeyan ijọba ibilẹ Ọsẹ laarin oṣu yii nikan.

Abule Mọlege ni wọn kọkọ lọ ní nnkan bii ọsẹ meji sẹyin, nibi ti wọn ti paayan mẹta, ti wọn si tun dana sun ọpọlọpọ ile awọn olugbe ibẹ.

Ọsẹ to kọja lawọn janduku darandaran naa tun lọ si Arimọgija, ti wọn si tun yinbọn pa awọn marun-un yatọ sawọn to tun fara gbọta lọwọ wọn.

Ọkan ninu awọn eeyan agbegbe Ọsẹ to ba wa sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Ọgbẹni Alaofin, ni ọrọ awọn Fulani ọhun ti kọja ohun to yẹ kijọba fọwọ yẹpẹrẹ mu.

O ni asiko ti to fawọn eeyan ilu Okelusẹ ati Ute lati fọwọsowọpọ, ki wọn si gba ara wọn silẹ lọwọ awọn ajoji godogbo to fẹẹ maa pa wọn bii ẹni pa ẹran nitori pe yoo soro pupọ fawọn to wa lokeere lati maa lọ siluu abinibi wọn ti akọlu naa ba ṣi n tẹsiwaju.

Leave a Reply