Fulani tun ji awọn mẹta n’Igangan, miliọnu mẹwaa ni wọn n beere

Faith Adebọla, Eko

Bi kii ba ṣe ori to ko ẹni kẹrin yọ, to fi raaye sa mọ wọn lọwọ, awọn mẹrin ni iba wa lakata awọn ajinigbe ti wọn ṣọsẹ niluu Igangan lọjọ Aiku, Sannde yii, awọn ajinigbe naa si ti sọ pe miliọnu mẹwaa naira lawọn maa gba lori awọn mẹta ti wọn ji gbe.

Orukọ awọn mẹtẹẹta ti wọn ji gbe ni AbdulGafar Ọlagunju, Kazeem Fasaasi, ati Ọladimeji Kabiru.

Ọgbẹni Abedeen Oguntowo, akọwe ẹgbẹ awọn ọdọ ilu Igangan, sọ fakọroyin wa lori aago pe niṣe lawọn ajinigbe naa fẹtan mu awọn ti wọn ji gbe ọhun.

O ni awọn mẹta yii ni wọn n sin maaluu ni agbegbe abule Idiyan, nitosi ilu Igangan, wọn agba alagbasin maaluu kan lati maa ba wọn mojuto o.

Owurọ ọjọ Sannde yii ni ọkan lara wọn gba ipe lori aago pe awọn ajinigbe ti ji alagbasin maaluu wọn gbe, awọn maaluu naa si ti fọn ka, ki wọn tete waa wo wọn kawọn maaluu naa ma baa sọnu sinu igbo. Itara aje yii lawọn mẹtẹẹta fi bẹ sori ọkada, ti wọn si sare lọ sibi iṣẹlẹ ọhun, lai mọ pe awọn gan-an lawọn ajinigbe naa lugọ de.

Wọn ni bo ti ku diẹ ki wọn yọ si apa ibi ti agbo maaluu wọn wa, lawọn ajinigbe rẹbuu wọn lọna, wọn si ji wọn gbe lọ.

Nibi ti wọn ti n ṣe wahala ọhun lọwọ ni ẹni kẹrin, Saheed, ti raaye sa mọ wọn lọwọ pẹlu ọkada to gun.

Owurọ ọjọ Aje, Mọnde yii, ni won too ri ọkan lara awọn ti wọn ji gbe naa ba sọrọ lori aago. O lori irin lawọn ṣi wa ninu igbo ti wọn ko awọn lọ, ati pe miliọnu mẹwaa naira lawọn ajinigbe naa lawọn maa gba ki wọn too le tu wọn silẹ.

Sa, Abedeen lawọn ti fi iṣẹlẹ yii to ọlọpaa leti. O lawọn OPC atawọn fijilante kan ti n tọpa awọn ajinigbe naa lọ, bo tilẹ jẹ pe inu ibẹru gidi lawọn mọlẹbi awọn ti wọn ji gbe wọyii wa.

Leave a Reply