Fulani tawọn ọlọpaa mu yii ti jẹwọ: Mo wa ninu awọn to yinbọn pa awọn ọba Ekiti

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Niṣe ni ọpọ awọn ọmọ orileede yii n lu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti, atawọn agbofinro ibilẹ bii Amọtẹkun lọgọ ẹnu fun iṣẹ akin ti wọn ṣe lati ṣawari diẹ ninu awọn ti wọn yinbọn pa awọn ọba alaye meji nipinlẹ Ekiti lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to kọja.

Ni bayii, ọkan ninu awọn afuarsi ọdaran to lọwọ ninu bi wọn ṣe yinbọn pa awọn ọba alaye meji ọhun nipakupa lagbegbe Ikọle Ekiti lọwọ awọn agbofinro ti tẹ lẹyin bii ọsẹ kan ti iṣẹlẹ ọhun waye.

Igbakeji ọga ọlọpaa patapata fun ipinlẹ Ekiti, Dare Ogundare, lo fidi eyi mulẹ lasiko to n ṣe afihan afurasi ọdaran ọhun ti wọn p’orukọ rẹ ni Baboga Alhaji fawọn oniroyin niluu Ado-Ekiti, lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹrin, oṣu Keji, ọdun 2024 yii.

Ogundare ni o na apapọ awọn ẹṣọ alaabo ipinlẹ naa ni ọpọlọpọ wahala ki wọn too ri ọdaran ọhun mu lasiko ti awọn n fọ awọn aginju to wa laarin Ayedun ati Ayebọde, nipinlẹ Ekiti.

O ni afuarsi ọhun ti fẹnu ara rẹ jẹwọ pe oun mọ nipa bi wọn ṣe ran awọn ọba mejeeji s’ọrun, ti akitiyan awọn ẹṣọ alaabo si n tẹsiwaju lati ri awọn ẹgbẹ rẹ yooku mu laipẹ rara.

Nigba tawọn oniroyin n fọrọ wa afurasi ọdaran ọhun lẹnu wo, oun funra rẹ jẹwọ pe loootọ loun wa lara awọn to pa Onímòjò ti Ìmòjò-Èkìtì, Ọba Ọlatunde Samuel Oluṣọla, ati Ọba David Babatunde Ogunṣakin, Ẹlẹ́ṣùn-ún ti Ẹ̀ṣùn-Ekiti, lasiko ti wọn n pada bọ nibi ipade kan ti wọn lọọ ṣe niluu Ìrélé Ekiti, lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2024.

Lori ọrọ awọn akẹkọọ atawọn olukọ ‘The Apostolic Faith’ ti wọn ṣẹṣẹ tu silẹ lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹrin, oṣu Keji yii, Ogundare ni awọn agbofinro ko ti i ri ẹnikẹni mu lori iṣẹlẹ naa, bo tilẹ jẹ pe loootọ lọwọ awọn tẹ awọn afurasi kan lasiko ti awọn ẹṣọ alaabo n fọ awọn aginju to wa lagbegbe Oke-Ọṣun, nitosi Ikẹrẹ-Ekiti, Igbo Ọ̀kà ati Iju si Ikẹrẹ-Ekiti.

O ni ohun ko le sọ ni pato boya wọn san owo fawọn ajinigbe ọhun ki wọn too tu awọn eeyan naa silẹ tabi wọn ko san, ṣugbọn ileeṣẹ ọlọpaa ki i gba ẹnikẹni nimọran ki wọn san iru owo bẹẹ.

Leave a Reply