Latari ẹsun ole ti wọn fi kan an, Lizzy Anjọrin ṣalaye ara ẹ

LizzyliFaith lizzylAdebọla 

Ko jọ pe ohun ti gbajumọ oṣere-binrin onitiata ilẹ wa nni, Elizabeth Anjọrin, tawọn eeyan mọ si Lizzy Anjọrin reti lohun to n ṣẹlẹ si i lasiko yii, pẹlu bi abuku ati ẹsin ṣe ba a lalejo, niṣe ni wọn fẹsun kan obinrin naa pe o ṣe afọwọra, wọn lo lọọ jale goolu atawọn ẹṣọ obinrin lọja nla kan n’Isalẹ Eko, lakara ba tu sepo, lọrọ naa ba lu sori ẹrọ ayelujara.

Ṣe wọn ni eegun to ba ti jade ti kuro ni ‘aiwo o’, ninu fidio iṣẹlẹ ọhun to n lọ yika lori ẹrọ ayelujara lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ karun-un, oṣu Keji yii, wọn ṣafihan arẹwa oṣere ọhun ninu ṣọọbu ti wọn ti n ta goolu ati kupa, awọn nnkan iṣaraloge obinrin, ṣọọbu nla ni, bẹẹ ni Lizzy wa laarin awọn ero nibi ti idarudapọ ti waye latari iṣẹlẹ yii, bẹẹ lawọn eeyan n bu u, bawọn kan ṣe n fa a laṣọ, lawọn kan n pe e lole, wọn ni ki wọn jẹ kawọn da omi gbigbona le e lori, wọn ni ko ṣẹṣẹ maa ṣe e, Ọlọrun lo mu un, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Oniroyin ori ẹrọ ayelujara kan to saaba maa n ṣofofo awọn oṣere, Gistlover, sọ kọ ọrọ sabẹ ọkan lara awọn fidio iṣẹlẹ ohun pe:

“O tun ti ṣẹlẹ o, ẹsin de o, aa, ọwọ tẹ Lizzy Anjọrin loni-in o nibi to ti lọọ jale, o ti n ṣe e tipẹ. Niṣe lo lọọ fi ayederu alaati banki sanwo fun goolu to ra l’Ekoo. Wọn ni ko ṣẹṣẹ maa ṣe bẹẹ, ti eleyii fi bu u lọwọ. Fidio oriṣiiriṣii lawọn eeyan ya nibi iṣẹlẹ naa, eleyii gbona fẹlifẹli ni o. Mo n bọ o, Lizzy ole ajibole.”

Awọn kan tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ pe loootọ ni, alaati ti Lizzy fi sanwo goolu olowo nla to ra ki i ṣe ojulowo atẹjiṣẹ banki, wọn ni agbelẹrọ ni, tori owo naa ko wọle, amọ obinrin naa sọ pe oun kọ loun ṣe kinni naa, o ni ọkọ oun lo fowo ṣọwọ, wọn niṣe lo n wo kami-kami-kami pẹlu iyanu nigba ti wọn fẹsun kan an.

Amọ ṣa o, lẹyin tọrọ naa di awuyewuye, Lizzy Anjọrin ti ṣe fidio kan nibi to ti ṣalaye bọrọ ọhun ṣe jẹ gan-an. O kọkọ fẹsun kan ẹnikan to pe ni Ṣẹpẹtẹri, pe oun lo wa nidii ọrọ ọun, oun ni ọta oun, to n ṣọ oun lọwọ lẹsẹ lati dọdẹ oun, lati fabuku kan oun, o loun naa si n ṣọ ọ.

Awọn eeyan ni Iyabọ Ojo, gbajumọ onitiata toun ati Lizzy ti sọ ara wọn di ekute ati ologbo ni obinrin naa n pe ni Ṣẹpẹtẹri.

Lẹyin naa ni Lizzy fi adalu ede oyinbo ti wọn n pe ni Pidgin ati Yoruba ṣalaye ara ẹ, o ni ki i ṣe goolu tabi nnkan eelo obinrin loun ra ni ṣọọbu naa, bawọn kan ṣe n gbe e kiri, o ni ninu oṣu Kọkanla, ọdun 2023 to kọja, lọjọ kẹtadinlogun ẹ loun lọọ ra awọn eroja iṣẹ telọ toun n ṣe lọja Idumọta, awọn nnkan ti wọn n lẹ mọ aṣọ bii stone atawọn oriṣii rubber kan ni, gbogbo owo naa si jẹ ẹgbẹrun mọkanlelaaadọrun-un naira, (N91,000). O lọkọ oun lo ṣe tiransifaa owo naa si ọkunrin to taja foun, ọlọja naa si sọ pe owo ti wọle, lo fi gbe ọja toun ra foun. Amọ lẹyin oṣu meji, iyẹn lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ karun-un toun lọ si ṣọọbu naa, ni ọlọja yii sọ foun pe owo ọjọsi naa ko wọle. O loun bii pe ki nidii ti ko fi sọ foun latọjọ yii, loju-ẹsẹ si loun ti sọ ohun to ṣẹlẹ fun ọkọ oun, ti ọkọ Lizzy Anjọrin si sọ pe oun yoo fi owo mi-in ranṣẹ, awọn yoo si maa lọ yanju owo ti akọkọ pẹlu banki lati mọ ibi to ha si. Amọ, ni gbogbo asiko ti eyi n ṣẹlẹ, awọn eeyan ti n korajọ, wọn ti n fẹẹ ṣe akọlu soun, wọn ti n sare ya fidio, wọn ti n pe oun lole, wọn si fẹẹ mu oun jokoo bii ẹni tọwọ tẹ, loun fi taku mọ wọn lọwọ. O ni gbogbo ohun to ṣẹlẹ yii, Ṣẹpẹtẹri atawọn ẹmẹwa ẹ ni wọn ṣe e. O ni bi Ṣẹpẹtẹri ṣe ṣe fun Ṣẹun Ẹgbẹgbẹ nigba kan niyẹn, ti wọn fẹsun lilu awọn onipaṣipaarọ owo ni jibiti kan an, ti wọn si ran ọkunrin naa lẹwọn, o ni nnkan ti wọn fẹẹ ṣe foun niyẹn, amọ aṣiri wọn ti tu.

Oriṣiiriṣii ọrọ lawọn eeyan ti sọ nipa iṣẹlẹ yii. Bawọn kan ṣe n gbe sẹyin Lizzy, bẹẹ lawọn mi-in n ta ko o.

Blossommiching ni “Ijọba ni lati wa nnkan ṣe sọrọ Iyabọ Ojo yii kẹ, bẹẹ naa lo ṣe akoba fun Baba Ijẹṣa.”

Soup_Palazzo ni: “Bawo lo ṣe waa mọ deeti ati akọsilẹ owo ti ko wọle naa lori foonu rẹ, nigba too sọ pe ọkọ ẹ lo ṣe tiransifaa naa? Mi o mọ boya awọn ẹlomi-in kiyesi koko yii ninu ọrọ rẹ.”

Derickose28 ni: “Obinrin yii lowo lọwọ ju ẹni to maa lọ jale lọ. Gbogbo yin kan fẹran lati maa gbọ iroyin abosi nipa awọn eeyan. Mi o kii ṣe ọkan lara awọn ololufẹ ẹ o, amọ ẹyin naa ẹ jẹ ka wo o, odidi ẹni to ni ṣọọbu itaja nla ti ara ẹ, awada ni gbogbo ẹsun yii jare.

Kiitan ni: Makan-makan loye n kan lọrọ ayelujara, ti Ṣẹpẹtẹri naa maa to ṣẹlẹ laipẹ.  

Precious sọ pe: Irọ ni, loootọ mo mọ pe asọrọ-sọ-boto ẹda kan ni, ṣugbọn gbogbo wa la mọ pe ko le lọọ jale. Tẹẹ ba mọ ọn deledele, bọrọkinni eeyan ni o.

Chinny ni “ṣe ootọ lọrọ yii ni, abi wọn fẹẹ mu wa nigan-an. Boya ere oniṣẹju perete kan ni wọn fẹẹ fi ṣe, ko tiẹ ye mi. Ẹ jẹ ki n mọ bo ba ṣe jẹ o.

Bẹẹ ni Mustymọni ni, eleyii ki i ṣe oju lasan o, pẹlu gbogbo bobinrin yii ṣe n lenu bebeebe lori ẹrọ ayelujara, ṣiọ!

Ẹnikan tun ni “ogun abẹnu ti n ba a ja. Ko loogun arinya, o lọọ n jẹ aayan, o ga o”

Leave a Reply