Fun ẹsun pe o yiwee, o tun parọ ọjọ ori, Enahoro wọ Tinubu lọ si kootu

Lọjọ kẹwaa, oṣu Kọkanla, ọdun yii, ni agbẹjọro kan, Mike Enahoro-Eba, wọ oludije funpo aarẹ labẹ ẹgbẹ All Progressives Congress (APC), Aṣiwaju Bọla Tinubu, lọ si kootu. Ẹsun to fi kan an ni pe o yiwee ẹri rẹ, o purọ ọjọ ori rẹ, o si bura eke labẹ ofin.

Ile-ẹjọ Majistreeti to wa ni Wuse Zone 6, niluu Abuja, lo ti fi ẹsun iwa ọdaran mẹta ọtọọtọ kan oludije APC yii.

Ninu iwe ipẹjọ naa to ni nọmba CR/121/2022, CR/122/2022 ati CR/123/2022, lo ti jẹ pe Tinubu nikan ni olujẹjọ to fi ẹsun naa kan.

Enahoro-Eba ni awọn iwe kan ti oun gba lati ileewe giga Chicago University, ni orileede Amẹrika, nipasẹ agbẹjọro oun ni Amẹrika, Matthew J. Kolwals fi han pe awọn ohun to wa ninu iwe naa yatọ si awọn akọsilẹ ti Tinubu ṣe sinu fọọmu afidafiiti EC-9 to fun ajọ eleto idibo ilẹ wa ni ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹfa, ọdun yii.

O ni iwe-ẹri ileewe giga Fasiti Chicago ti awọn alaṣẹ ileewe naa gbe sita yatọ si eyi ti Tinubu fi silẹ fun ajọ eleto idibo.

Ọkunrin naa ni beeyan ba gbe iwe-ẹri naa sẹgbẹẹ ara wọn, awọn deeti to wa nibẹ ko papọ, ọkan jẹ ojọ kejilelogun, oṣu Kẹfa, nigba ti ekeji jẹ ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹfa, ọdun 1979. (June 22, 1979 ati June 27, 1979). O ni ami idanimọ ileewe naa (logo) ọtọọtọ lo wa lori awọn iwe-ẹri naa, ọtọọtọ ni iṣowọkọwe ati agbekalẹ ti wọn lo lati fi kọ satifikeeti mejeeji, bẹẹ ni ọtọọtọ lawọn to buwọ lu iwe-ẹri mejeeji.

Ni afikun si awọn ẹsun rẹ, ọkunrin yii ni ninu fọọmu igbaniwọle to fẹẹ fi wọ Yunifasiti Chicago to fọwọ si lọdun 1977, iwe esi idanwo kan lati Southwest College, Chicago, lo fi sinu fọọmu rẹ yii. Orukọ to wa nibẹ ni ‘Tinubu Bọla A’, eyi to si fi han pe obinrin lo ni esi idanwo naa, leyii to yatọ si ohun to kọ sinu fọọmu idije rẹ, iyẹn form EC-9 to fi ranṣẹ si ajọ eleto idibo, nibi to ti ni ọkunrin loun.

Siwaju si i, Lọọya Enahoro-Eba ni bakan naa ni Tinubu sọ pe oun lọ si ileewe girama Government College, Eko, lọdun 1970, ṣugbọn ti ko ri iwe-ẹri kankan fi silẹ lati gbe eleyii lẹsẹ ninu foọmu to fọwọ si fun ajọ eleto idibo yii.

Ninu iwe ipẹjọ, CR/121/2022, Enahoro sọ pe ayederu iwe-ẹri Chicago University ni Tinubu fun ajọ eleto idibo pẹlu ero lati lo o bii pe ojulowo ni.

Agbẹjọro Eba ni pẹlu eyi to ṣe yii, o ti jẹbi ẹsun iwe yiyi, eyi to wa labẹ ofin ilẹ wa, 362 (a), 363 ati 364, ti i ṣe ofin iwa ọdaran to lodi sofin ti olu ilu orileede Naijiria to wa ni Abuja.

Ọjọ kẹsan-an, oṣu Kọkanla lo kọ iwe ẹsun naa, ọjọ kẹwaa, osu naa lo gbe e lọ si kootu.

Ki i ṣe agbẹjọro yii nikan ni yoo kọkọ fi ẹsun iwe yiyi tabi ayederu iwe ẹri kan oludije APC yii. Ọpọ awọn ẹgbẹ ajafẹtọọ atawọn agbẹjọro mi-in, to fi mọ awọn ẹgbẹ oṣelu alatako paapaa ni wọn ti gbe Tinubu lọ si kootu lori awọn kudi-ẹ kudi-ẹ ti wọn lo wa ninu awọn iwe to ko silẹ fun INEC, bii ọjọ ori rẹ, awọn ileewe to lọ ati bo ṣe ri awọn owo rọgunrọgun to wa lọwọ rẹ.

Bo tilẹ jẹ pe igbẹjọ ti bẹrẹ lori awọn kan ninu ẹsun yii, gbogbo eeyan lo n duro de igba ti igbẹjọ yoo bẹrẹ lori ẹsun tuntun ti wọn tun fi kan an yii.

Leave a Reply