Awọn ọlọpaa tilẹkun ileegbimọ aṣofin Ekiti pa

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti ti paṣẹ pe ki wọn ti ilẹkun ile naa pa, bakan naa ni wọn ni ki awọn ọlọpaa gba isakoso gbogbo agbegbe naa. Eyi ko sẹyin bi Kọmiṣanna wọn,  Adesina Moronkeji, ṣe so pe oun gbọ pe awọn janduku oloṣelu kan n gbero lati waa da wahala silẹ nibẹ lori bi wọn ṣe yan Ọnarebu Gboyega Aribisọgan gẹgẹ bii olori ile naa tuntun.

Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, oṣẹ yii ni awọn aṣofin naa yan Ọnarebu Gboyega Aribisọgan lasiko eto idibo ranpẹ kan to waye lati yan ẹlomi-in dipo olori wọn to ku, Funminiyi Afuyẹ. Nibẹ ni wọn ti fi ibo mẹẹẹdogun gbe e wọle, to si fi ẹyin Arabinrin Olubunmi Adelugba to n ṣoju ijọba ibilẹ Emure nileegbimọ aṣofin naa janlẹ.

Eyi la gbọ pe ko dun mọ awọn kan ninu. Wọn ni Dokita Kayọde Fayẹmi lo fa Adelugba kalẹ, awọn ọmọ ẹyin rẹ ko si fara mọ bi ẹni ti ọga wọn n ṣaltilẹyin fun yii ko ṣe wọle. Eyi ni ALAROYE gbọ pe wọn fi n gbimọ lati waa da ileegbimọ naa ru.

Ṣugbọn awọn agbofinro tete fura. Lati dena wahala to le ṣẹlẹ lo mu ki wọn ti ibẹ pa, ti wọn si ko awọn agbofinro si gbogbo ayika ibe.

Awọn agbofinro ko jẹ ki awọn oṣiṣẹ ileegbimọ naa raaye wọle, niṣe ni wọn duro si ẹnu ọna ile yii, bakan naa ni wọn tu duro si gbogbo ayika ibẹ pẹlu ibọn atawọn ohun ija miiran lọwọ. N lawọn oṣiṣe yii ba pada sile ni tiwọn.

Ọkan lara awọn aṣofin naa to ba awọn akọroyin sọrọ sọ pe aṣẹ lo wa lati ọdọ awọn ọlọpaa pe ki onikaluku maa lọ sile lati faaye gba alaafia.

Ṣugbọn nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ ọhun, Abẹnugan ti wọn ṣẹṣẹ yan, Aribisọgun, sọ pe ko si wahala tabi rogbodiyan nileegbimọ naa.

O ni, “Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ekiti lo pe wa laaarọ yii pe oun gbọ pe awọn janduku oloṣelu kan fẹẹ ya bo ile naa, o ṣalaye pe ki eleyii ma baa ṣẹlẹ lawọn ọlọpaa ṣe paṣẹ pe ki awọn oṣiṣẹ ati aṣofin pada sile wọn.

“Mo fi asiko yii rọ gbogbo oṣiṣẹ ati awọn ẹlẹgbẹ mi pe ki wọn ni suru, ohun gbogbo yoo pada bọ sipo.

Leave a Reply