Otẹẹli tawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun yii ti n ṣepade lọlọpaa ti ko wọn l’Agege

Faith Adebọla

Afi bii igba ti ogunna bọ somi, bẹẹ ni gbogbo ariwo ati igbokegbodo awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun mọkanla ṣe wẹnlo, nigba tọwọ awọn agbofinro ba wọn loru mọju Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kọkanla yii, nibi ti wọn ti n ba ara wọn ja ni otẹẹli kan, lagbegbe Agege, nipinlẹ Eko.

Ko sẹni to mọ pato ohun to dija laarin wọn, ṣugbọn gẹgẹ bi Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, SP Benjamin Hundeyin ṣe sọ, bo tilẹ jẹ pe ko darukọ ati ọjọ-ori awọn afurasi ọdaran yii, o ni nnkan bii aago mẹta ku iṣẹju mẹẹdogun laajin oru lawọn ọlọpaa ikọ ayara-bii-aṣa, iyẹn Rapid Response Squard, eyi ti CSP Ọlayinka Ẹgbẹyẹmi n dari, sare lọọ sibi iṣẹlẹ naa, nigba ti wọn gbọ gbajare awọn to mule gbe otẹẹli ọhun, pe ki wọn waa wo ohun to n ṣẹlẹ.

O ni nigba tawọn ọlọpaa fi maa debẹ, mẹrin ninu awọn ẹlẹgbẹkẹgbẹ yii ti ṣe ara wọn leṣe, niṣe ni ẹjẹ n da lara wọn, ti wọn ti fi ọbẹ atawọn nnkan ija oloro mi-in ya ara wọn yanna-yanna, ṣokoto wọn si ti rin gbindin fun ẹjẹ, tori gbogbo ko sẹwu lọrun gbogbo wọn.

Wọn ni bawọn ọlọpaa ṣe yọ sibẹ lojiji, niṣe lawọn afurasi ọdaran naa bẹ lugbẹ, wọn sa lọ, ṣugbọn ọwọ tẹ mọkanla lara wọn, wọn pẹlu awọn nnkan ija bii ọbẹ, ada, ati egboogi oloro ti wọn ba lapo wọn.

Wọn ti ko wọn lọ si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to wa l’Agege, ni Oko-Ọba, wọn si ti lọọ fiṣẹlẹ naa to Kọmiṣanna  ọlọpaa Eko, CP Abiọdun Alabi, leti, ki iwadii le bẹrẹ, ki wọn too foju wọn bale-ẹjọ.

Leave a Reply