Funmi ji ọmọ ti wọn ṣẹṣẹ bi gbe l’Okitipupa, nibi ti wọn ti n sọ ọ lorukọ ni Sagamu lọwọ ti tẹ ẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọwọ awọn ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti tẹ obinrin ẹni ọdun marundinlogoji kan, Funmi Gbojuri, lori ẹsun pe o ji ọmọ ikoko kan gbe niluu Okitipupa lọsẹ to kọja.

Alukoro ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Funmilayọ Ọdunlami,  ṣalaye fawọn oniroyin lasiko ti wọn n ṣe afihan afurasi ajọmọgbe ọhun ni olu ileesẹ wọn l’Akurẹ nirọlẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja yii pe baba ọmọ tuntun naa lo lọọ fẹjọ sun ni tesan ọlọpaa to wa l’Okitipupa, pe ẹnikan ti ji oun lọmọ gbe sa lọ.

O ni lẹyin ọjọ diẹ ti awọn ti kẹsẹ bọ iwadii iṣẹlẹ ọhun lọwọ pada tẹ Funmi ati ọmọ ọwọ naa nibi kan ti wọn n pe ni Makun, nitosi Sagamu, nipinlẹ Ogun.

Ọdunlami ni ọmọbìnrin ọhun pada jẹwọ fawọn agbofinro pe loootọ loun ji ọmọ naa gbe wa sile ọkunrin kan, Ọdunayọ Ayọbami, ẹni to pe ni ọkọ rẹ.

O ni awọn tun fidi rẹ mulẹ ninu iwadii awọn pe o ti kọkọ ji ọmọ kan gbe l’Okitipupa yii kan naa lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kin-in-ni, ọdun 2021, eyi to lọọ gbe fun ọkunrin mi-in to pe ni Lucky, ẹni to fi ilu Igbọkọda, nijọba ibilẹ Ilajẹ, ṣebugbe.

Ọmọbinrin ọhun lo ni o ṣalaye fawọn pe oun ti bimọ meji tẹlẹ fun ọkunrin kan lasiko toun wa lorilẹ-ede Cameron, ṣugbọn to jẹ pe aitete rọmọ mi-in bi fawọn ọkunrin ti oun n fẹ lẹyin toun pada wa si Naijiria lo ṣokunfa bi oun ṣe n ji awọn ọmọ ọlọmọ gbe fun awọn ọkọ oun.

Ninu ọrọ ṣoki ti afurasi ọhun funra rẹ sọ lasiko tawọn oniroyin n fọrọ wa a lẹnu wo, o ni ifẹ toun ni sawọn ọmọ tuntun latari airọmọbi oun loun ṣe n ji wọn gbe.

 

Afurasi ọhun ni kawọn ọmọ Naijiria atawọn agbofinro fiye denu, ki wọn si foriji oun, nitori pe ko ye oun rara pe iwa ti oun n hu ko bojumu.

Leave a Reply