Ọga ileewe kan, Abdulmalik Tanko Mohammed ti aṣiri rẹ ṣẹṣẹ tu pe o pa akẹkọọ rẹ, Hanifa Abubakar, ti ko ju ọmọ ọdun marun-un lọ lẹyin to gba ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un Naira ninu miliọnu mẹfa to beere fun lọwọ awọn obi rẹ sọ pe oogun ekute ọgọrun-un naira loun po papọ mọ ounjẹ ti oun fi pa ọmọ naa. O fi kun un pe owo ile ti oun n lo lati fi ṣe ileewe naa ti oun ko ti i ri san lo fa a ti oun fi j i ọmọ naa gbe.
Mohammed lo n ka boroboro lolu ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Bompai, niluu Kano, lọjọ Ẹti, Furaidee, opin ọsẹ yii, ti awọn ọlọpaa n ṣafihan rẹ.
Ọkunrin to ni oun loun ni ileewe naa ṣalaye pe owo ile ti oun n lo lati ṣe ileewe naa ti too san, oun ko si lowo lọwọ lati fi san an. Eyi lo mu ki oun ji ọmọ naa gbe pẹlu erongba pe oun yoo fi owo ti oun ba gba nidii ijinigbe naa sanwo ọhun.
O ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un Naira loun gba lọwọ awọn obi ọmọ yii loootọ, owo ile naa loun si fi san. Ṣugbọn ko tori ẹ tu ọmọ naa silẹ. O ni nitori pe ọmọ naa da oun mọ, o si le lọọ tu oun fo lọdọ awọn obi rẹ.
Tanko ni oogun ekute ọgọrun-un kan Naira loun ra toun po mọ ounjẹ ti oun fun ọmọ naa. Leyin to jẹ ounjẹ ti majele wa ninu rẹ yii tan lo ku.