Gbogbo awọn to pa ọlọpaa, ti wọn tun jo teṣan wọn nina, la maa fi jofin- Kọmiṣanna Ọyọ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ọga agba ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CP Joe Nwachukwu Enwonwu, ti ṣeleri pe gbogbo awọn to lọwọ ninu bi wọn ṣe pa awọn ọlọpaa, ti wọn tun jo awọn teṣan ọ̣lọpaa kan nina pata lọwọ awọn maa ba, ti awọn si maa fi iya to tọ́ jẹ wọn labẹ ofin.

CP Enwonwu sọrọ yii lasiko to n gbalejo ẹgbẹ Ọyo State Leading Patriot lọfiisi ẹ to wa l’Ẹlẹyẹle, n’Ibadan. Nirọlẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii ni wọn ṣabẹwo si i lati ki i ku atemọra awọn ọlọpaa ti wọn padanu ẹmi wọn ninu ọkan-o-jọkan laasigbo to waye lọsẹ to kọja.

Tẹ o ba gbagbe, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ to kọja, lawọn ọmọ iṣọta to dara pọ mọ awọn olufẹhonu han nipa awọn aiṣedeede to n lọ lawujọ, ti wọn si lo anfaani naa lati dana sun agọ ọlọpaa mejeeji to wa laduugbo Ọjọọ, n’Ibadan, lẹyin ti wọn ti bẹ ọlọpaa kan lori, ti wọn si dana sun awọn meji mọ inu ọfiisi wọn nibẹ.

Lọjọ kẹta ti i ṣe Ọjọbọ, Tọsidee lawọn mi-in tun dana sun ọlọpaa meji laaye laduugbo Iwo Road, n’Ibadan, ti wọn si tun dana sun agọ ọlọpaa to wa laduugbo Alabẹbẹ, nitosi Mọnatan, n’Ibadan, kan naa.

Bakan naa lawọn janduku ọdọ kan ya wọ agọ ọlọpaa ilu Isẹyin, ti wọn si gbe awọn ibọn awọn agbofinro to wa nibẹ lọ ko too di pe wọn dana sun teṣan naa.

Olori ẹgbẹ ọdọ to ṣabẹwo ibanikẹnun naa, Aṣiwaju Nurudeen Akinade, ẹni to ko awọn ọdọ bii mẹẹẹdogun sodi ninu irinajo ọhun sọ pe, “Ta a ba wo gbogbo ohun to ti n ṣẹlẹ lati ọsẹ bii meloo kan, a a ri i pe ilu o fara rọ. Wọn n paayan lọtun-un  losi, wọn n fọ ile onile, ja ṣọọbu oniṣọọbu. Wọn tiẹ jo awọn ọlọpaa kan nina laaye. Iyẹn la ṣe wa lati ba ọga wọn kẹdun araferaku awọn eeyan wọn to ba awọn rogbodiyan yii lọ.’’

Nigba to n fi ẹmi imoore han si awọn olubanikẹdun naa, ọga agba awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CP Joe Nwachukwu Enwonwu sọ pe “o dun mi pe ko si ẹni to jade si gbangba lati bu ẹnu atẹ lu ipaniyan ati iwa ọdaran gbogbo ti awọn janduku kan hu yii. Iyẹn lo ṣe ya ni lẹnu pe a ṣi ri awọn ọmọ Naijiria rere to n ṣe eyi ti ẹ n ṣe yii.

“Eyi ti wọn ṣe yii ti kọja ọrọ pe wọn n binu, iwa ọdaran pọnbele ni wọn hu. Abi nigba tẹ ẹ le awọn ọlọpaa, ti awọn yẹn sa lọ fun yin, ṣe iyẹn ko ti i to, ẹ waa lọọ gbe ibọn wọn, ibọn ijọba apapọ. Ki lẹ fẹẹ fibọn ṣe bi ko ṣe lati maa fi huwa ọdaran. Idi ree ti ẹyin ọmọluabi awujọ ṣe ni lati fowọsowọpọ pẹlu awọn agbofinro lati ri awọn to ji ibọn AK 47 (ibọn awọn ọlọpaa) gbe.

Awọn eeyan yii ko gbọdọ lọ bẹẹ lai jiya nitori ọdaran ni wọn, wọn ko ni i jẹ ka gbadun lawujọ pẹlu awọn ibọn naa. A gbọdọ mu awọn ọdaran yii, bi bẹẹ kọ, ibọn ti wọn ji gbe yẹn ni wọn aa fi maa pa awọn eeyan kaakiri ilu. Wọn kan le sa lọ ni, wọn ko le mu ijiya jẹ.”

2 thoughts on “Gbogbo awọn to pa ọlọpaa, ti wọn tun jo teṣan wọn nina, la maa fi jofin- Kọmiṣanna Ọyọ

 1. Agbo gbogbo Atotonu tiwon Lori Oro yi ?
  Sungbon edakun Tori Olohun.Awon ti Awon Agbofinro naa pa nko.
  Kileose pelu awon yan ooo.
  Emi je Omobibi ilu iseyin
  Ibanuje nlanla loje funwa Lori isele ti ileese olopa ti wonjo ninnan paapajulo pelu ofo nlanlan ti Awon tosise yi se latari fifi ehonu iro han sise laabi yi ??.
  Sungbon ju gbogbo e lo.
  Aro awon ijoba wa kinwon bawa se Atunse lonan kinnin keji ki gbogbe o lee joraawon boseto ati boseye ???

  Aki ileise Alaroye
  Konii suuyin kosi Ni Reyin ooooooo ?

Leave a Reply