Ibo alaga kansu Ọyọ: PDP ti wọle nijọba ibilẹ mejilelọgbọn

Ọlawale Ajao, Ibadan

Gbogbo awọn ondupo to dije lorukọ ẹgbẹ oṣelu People’s Democratic Party, PDP, ninu idibo ijọba ibilẹ to waye lojo Abamẹta, Satide, to kọja yii, ni wọn jawe olubori sipo kansilọ ati ipo alaga kansu kaakiri ijọba ibilẹ mẹtẹẹtalelọgbọn (33) to wa nipinlẹ Ọyọ.

Wọn ko ti i dibo ijọba ibilẹ Ido, Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, ni Aarẹ Isiaka Abiọla Ọlagunju ti i ṣe alaga ajọ eleto idibo ipinlẹ yii (Oyo State Independent Electoral Commission, OYSIEC) sun atundi ibo ijọba ibilẹ Ido si bayii. Eyi waye nitori bi ajọ eleto idibo ṣe gbagbe lati fi orukọ ẹgbẹ oṣelu ZLP sinu iwe idibo naa.

Bakan naa ni wọn yoo tun idibo kansilọ di ni Wọọdu karun-un, niluu Eruwa, nijọba ibilẹ Ila-Oorun Ibarapa.

Ṣaaju lalamoojuto eto idibo ijọba ibilẹ naa, Ọgbẹni Thomson Iṣọla, ti royin iṣẹlẹ to mu ki wọn fagile idibo kansilọ naa.

O ni “A bẹrẹ idibo daadaa, ohun gbogbo si n lọ deede gẹgẹ bo ṣe yẹ ki eto idibo gidi ṣe lọ. Nigba to di ọsan la gbọ pe awọn tọọgi ti da eto idibo ru nibudo idibo kẹta, ni wọọdu karun-un. A ṣewadii, a si gbọ pe ootọ ni, wọn ti ba gbogbo ibudo idibo wọọdu agbegbe Eruwa Tuntun, niluu Eruwa jẹ.

“Awọn tọọgi gbe iwe idibo sa lọ nibudo idibo keje, ni Wọọdu karun-un yìí kan naa. A si pinnu lati fagi le awọn ibo wọọdu yẹn.”

Eyi ni abajade esi idibo naa pẹlu iye ibo ti ẹgbẹ oṣelu PDP ni ninu idibo alaga ijọba ibilẹ kọọkan ati orukọ awọn alaga tuntun naa ti wọn yoo tukọ ijọba ibilẹ kaluku wọn fun odidi ọdun mẹrin si asiko yii.

ITẸSIWAJU

PDP:15,875

Ojo Bọlaji

ISẸYIN

PDP: 39,275.

Ọnarebu Oṣuọlale

KAJỌLA

PDP: 21,933.

Afọlabi A. Adebayọ

IWAJỌWA

PDP 15,614

Oyinloye Jẹlili Adebare

ATISBO

PDP: 20,871.

Adeagbo Fasasi Ademọla

ILA-OORUN ṢAKI

PDP: 16,064.

Adediran A. Mosunmade

IWỌ-OORUN ṢAKI

PDP: 29,797

Muideen Sarafadeen

OORELOPE

PDP: 8580. Raheem Akeem Adepọju

IRẸPỌ

PDP: 21,677

Sulemana Lateef Adediran

ỌLỌRUNṢOGO

PDP: 10692

Akanni Juliana Olúwakẹ́mi

 

 

ARIWA OGBOMỌṢỌ (OGBOMỌṢỌ NORTH)

PDP: 23,008

Arẹmu Kabir Ayọade

GUUSU OGBOMỌṢỌ (OGBOMỌṢỌ SOUTH)

PDP: 23, 506

Oyeniyi Thimothy

OGO OLUWA

PDP: 14873

Ojo Oluwaṣeun Adesoye

 

ORIIRE

PDP: 23,016.

Alabi Ọlatẹju Michael

SURULERE

PDP: 22526

Adegbitẹ Isiah Alaba

AARIN-GBUNGBUN IBARAPA (IBRP CENTRAL)

PDP: 9,987.

Ọnarebu Oloyede

ARIWA IBARAPA (IBARAPA NORTH)

PDP: 20,222

Lawal Azeez Adewale

AFIJIO

PDP: 15,158

Sunday Akindele Ojo

ATIBA

PDP: 14,690

Ọnarebu Mojisọla Kafila Ọlakojọ

IWỌ-OORUN ỌYỌ (ỌYỌ WEST)

PDP: 16,888

Salami Babatunde Akeem

ILA-OORUN ỌYỌ (OYO EAST)

PDP: 17141

Arowoṣaye Saheed Adeyẹmi

ILA-OORUN ARIWA IBADAN IB. NORTH EAST

PDP: 19,408

Akintayọ Ibrahim Akinṣọla

AKINYẸLE

PDP: 38492

Jimoh Taoheed Adedigba

OLUYỌLE

PDP: 11,224

Settle Ọlaide Popoọla

LAGELU

PDP: 34,704

Gbadamọsi Kazeem Adeyẹmi

IWỌ-OORUN ARIWA (IBADAN N/W)

PDP: 18,298

Adepọju R.O.

ẸGBẸDA

PDP: 28,553

Sanda Sikiru Oyedele

IWỌ-OORUN GUUSU IBADAN (IBADAN SW)

PDP: 29,182

Kẹhinde Adeyẹmi Akande

ỌNA-ARA

PDP: 22,544

Sanusi Musibau Adeṣina

ARIWA IBADAN IB. NORTH

PDP. 37,135

YUSUF S. O.

ILA-OORUN ARIWA IBADAN (IB. SOUTH EAST)

PDP: 18,027

Alawode Oluwọle Emmanuel

PDP: 12,138

Ọbalọwọ O.A.

Pẹlu bi ẹgbẹ oṣelu yooku ṣe n mura silẹ de atundi ibido ijọba ibilẹ Ido ati idibo kansilọ wọọdi karun-un nijọba ibilẹ Ila-Oorun Ibarapa, ara ija ti ẹgbẹ oṣelu APC yoo ja ni kootu ni wọn n mu nitori bi idibo ọhun ṣe ku ọjọ bii mẹta ni wọn ti gba kootu lọ, wọn ni kile-ẹjọ paṣẹ fun  ijọba Gomina Makinde ti ipinlẹ Ọyọ lati ma ṣe ṣeto idibo naa nitori eto ọhun ko ni i yatọ si ifowo-ijọba-ṣofo lasan.

Leave a Reply