Adefunkẹ Adebiyi
Igbakeji gomina ipinlẹ Edo, Philip Shaibu, ti fi atilẹyin rẹ ati ti gbogbo ọmọ ipinlẹ Edo han si Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo lati di aarẹ Naijiria lọdun 2023.
Ọjọ Abamẹta, Satide, to kọja yii, ni Shaibu sọrọ yii laafin Otaru Auchi, nibi ti wọn ti fi Clem Agba, Minista ipinlẹ fun eto iṣuna owo joye Odumha ilu Auchi. Ọjọgbọn Ọṣinbajo si ni alejo pataki nibi ayẹyẹ naa.
Nigba to n sọrọ, Igbakeji gomina Edo naa sọ pe, “ Ọlọla ju lọ, ẹyin ẹ ṣaa gba pe ẹ ni Edo, ẹ ni wa. Gbogbo nnkan yoowu tẹ ẹ ba fẹẹ ṣe, ẹ ni wa, ẹ dẹ ni Ọlọrun. Pẹlu ogo Ọlọrun, eyi to jẹ tiwa yii lo maa di aarẹ Naijiria lọdun 2023.”
O fi kun ọrọ ẹ pe asiko ‘Baba sọ pe’ ti kọja o, asiko ta a wa yii, ti awọn adari rere ni, ti awọn onitẹsiwaju ni.
Shaibu sọ pe awọn eeyan to ni ori pipe lọrọ kan bayii, awọn to le yi nnkan pada, to bẹẹ ti awọn ti ko riṣẹ ṣe yoo fi dẹni to niṣẹ gidi lọwọ.
Bo tilẹ jẹ pe Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo ti i ṣe Igbakeji Aarẹ Naijiria lọwọlọwọ ko ti i sọ pe oun fẹẹ dupo aarẹ lọdun 2023, sibẹ, awọn ero ti pọ lẹyin rẹ rẹpẹtẹ, ariwo ti wọn n pa ni pe tiẹ lawọn n ṣe lọjọkọjọ